SON: Aṣọ ọmọ iléèwé tó n fa jẹjẹrẹ n bẹ l'ọ́jà ní Nàìjíríà

Ileewe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àwọn iléèṣẹ́ tó n lo èròjà nàá ní china ni Sing Shun Fat School-Clothier Company àti Zenith Uniform Company.

Àjọ tó n ṣe àyẹ̀wò bí àwọn nkan èlò tí wọ́n nko wọ Nàìjíríà láti ilẹ̀ òkèérè, tó fi mọ́ èyí tí wọ́n n ṣe l'ábẹ́lé, ṣe pójú owó sí, SON, ní àwọn aṣọ ọmọ iléèwé kan tó le fa àìsàn jẹjẹrẹ ti wọlé sí Nàìjíríà.

Ajọ Standard Organisation of Nigeria, SON, sọ pé àwọn aṣọ ọmọ ileewe kan tí àwọn òntàjà n kó wọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti China, ní àpọ̀jù aró kan tí wọ́n n pè ní ''azo''. Aró azo ni àwọn iléèṣẹ́ tó n ṣe aṣọ l'órílẹ̀-èdè China àti àwọn mi i nlò.

Àkọlé fídíò, PVC: Ṣé a ṣẹ̀ 'jọba la ṣe ń jìyà lóri káádì ìdìbò ni?

Àjọ nàá lójú òpó ayélujára rẹ̀ sọ pé àwọn èròjà kan maa n jáde lára ''azo'', tó sì le fa jẹjẹrẹ, tó bá fi dàpọ̀ mọ́ òógùn ara ènìyàn.

SON ṣàlàyé pé wọ́n ti fi òfin de azo ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè, ṣùgban àwọn iléèṣẹ́ méjì kan l'órílẹ̀-èdè China ṣi n lò ó.

Àwọn iléèṣẹ́ nàá ni Sing Shun Fat School-Clothier Company àti Zenith Uniform Company.

Awọn ọmọ ileewe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹ̀wẹ̀, àjọ SON ní kí gbogbo àwọn tó bá fẹ́ kó aṣọ àwọn ọmọ iléèwé wọlé sí Nàìjíríà kọ́kọ́ sọ fún àwọn, kí àwọn le ṣe ìwádíì rẹ̀ kí wọ́n tó ò ko wọ Nàìjíríà.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iléèwé ìjọba àti aládàáni ló n ra aṣọ̀ tí àwọn ọmọ iléèwé wọn n wọ̀ láti orílẹ̀-èdè China.