Europa: Arsenal yóò kojú Sporting, Chelsea yóò kojú PAOK Salonika

Alex Iwobi n waako pẹlu ikọ Chelsea

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ipele to kangun si aṣekagba ni Arsenal ti kuna ninu idije naa ni saa to kọja

Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal yoo maa koju ẹgbẹ agbabọọlu Sporting Lisbon ti Portugal ni ipin E ipele akọkọ idije Europa League ti ọdun yii.

Ninu eto ipin isọri ti ajọ ere bọọlu Yuroopu, UEFA ṣe ni ọjọ ẹti ni eyi ti farahan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ipin idije EUROPA fun saa 2018/2019

Awọn ẹgbẹ agbabọọlu miran ti Arsenal yoo tun maa waa ko pẹlu ni Arabag ti orilẹede Azerbaijan pẹlu Vorskla lati orilẹede Ukraine.

Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ni tirẹ yoo maa waa ko pẹlu PAOK Salonika lati orilẹede Greece, BATE Borisov lati orilẹede Belarus ati ẹgbẹ agbabọọlu Vidi lati orilẹede Hungary

Ipele to kangun si aṣekagba ni Arsenal ti kuna ninu idije naa ni saa to kọja lẹyin ti wọn fidirẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Athletico Madrid.