'Ohun tí àwọn adarí ilẹ̀ Europe fẹ́ jẹ ni wọ́n fi ń wá sí Nàìjíríà'

Angela Merkel ati Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, @FannyFacsar

Adarí orílẹ̀èdè Germany, Angela Merkel ní Ilẹ̀ Germany àti Naijiria yóò fọwọ̀sowọ́pọ̀ lórí ọ̀rọ̀ ajé

Olootu ijọba orileede Germany, Angela Merkel, ni o jẹ orileede oun logun lati pese awọn ilana to ba ofin mu fun awọn ọmọ Naijiria to fẹ ẹ rinrinajo lọ si orileede Germany.

Merkel sọ igbesẹ naa di mimọ nibi ipade ajumọṣe kan ti oun ati Aarẹ Naijiria, Muhammadu Buhari sẹ pẹlu awọn oniroyin nilu Abuja.

O fi kun ọrọ rẹ pe oun fẹ fi kun ẹgbẹẹfa (1,200) awọn ọmọ Naijiria to n kẹkọ ni orilẹede Germany. Ati pe orilẹede oun yoo tun imọ ijinlẹ nipa iṣẹ ọwọ ati imọ ẹrọ pẹlu Naijiria.

Amọ, abẹwo olootu ijọba Germany naa waye ni asiko ti awọn eniyan n fi ẹhọnu han lori ofin to de irina awọn eniyan wa si orilẹede Germany.

Lori eyi, Merkel ni oun ati Aarẹ Buhari fi ẹnu ko pe ipese iṣẹ nikan ni kan lo le fi opin si ṣiṣe fayawọ ọmọniyan ati irinajo si ilẹ okeere lọna aitọ.

Lọwọlọwọ, bi ọgbọn ẹgbẹrun ni awọn ọmọ Naijiria to n gbe ni orilẹede Germany lọna ti ko ba ofin mu.

Angela Merkel ati Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Chancellor orílẹ̀èdè Germany, Angela Merkel ti gúnlẹ̀ sí Naijiria fún ìbásepọ̀ tó dán mọ́rán láàárín Ilẹ̀ Germany àti Naijiria.

Lopin ipade naa, awọn olori orilẹede mejeeji fi ọwọ si iwe adehun igbọraẹniye lori eto ọgbin, ọkọ ṣiṣe, to fi mọ ipese owo yiya fun awọn agbẹ.

Angela Merkel ni olori orilẹede latilẹ okeere keji to bẹ Naijiria wo laarin ọsẹ yii.

Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Theresa May lo kọkọ lọ si ilu Abuja lati ri aarẹ Muhammadu Buhari l'ọjọru.

Kíni ìdí tí àwọn adarí ilẹ̀ Europe fi ń wá sí Nàìjíríà?

Àkọlé fídíò, Akin Oyebode: ohun tí wọ́n fẹ́ jẹ ni wọ́n ń wá

Onimọ nipa ofin ilẹ okeere ati abẹle, Ọjọgbọn Akin Oyebọde ti sọ wipe awọn adari ilẹ Europe n wa si orilẹede Naijiria nitori oun ti wọn o jẹ.

Láàárìn osu mẹ́ta, adarí mẹ́ta láti ilẹ̀ Europe, Emmanuel Macron tí ilẹ̀ Faranse, Theresa May láti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Angela Merkel láti ilẹ̀ Germany ti wá sí Naijiria.

Ọjọgbọn Oyebọde sọ eyi nigbati oun ba BBC Yoruba sọ ọrọ lori abẹwo adari Ilẹ Germany, Angela Merkel si olu-ilu Naijiria ni Abuja.

Àkọlé fídíò, Èmi ni Awùjalẹ̀ ti Iwo

O fikun wipe, wiwa ti awọn adari naa wa yoo bu iyi kun oriẹede Naijiria, yoo si tun mu ibugbooro ba ọrọ aje Naijiria, eleyii ti yoo bukun igbe aye awọn ara ilu Naijiria.

Àwọn adarí orílẹ̀èdè
Àkọlé àwòrán, Àwọn adarí orílẹ̀èdè

Amọ, Ọjọgbọn Akin Oyebode wa fikun wipe oseese ki wiwa ti awọn adari Ilẹ Europe yii n wa si Naijiria o fi agbara fun Aarẹ Muhammadu Buhari saaju idibo gbogboogbo ọdun 2019.

Merkel ti se abẹwo si awọn adari orilẹede Senegal ati ilẹ Ghana ni ọsẹ yii lati jiroro lori ibugboro ọrọ aje laaarin ilẹ Germany ati Iwọ-Oorun Afirika.