#NotTooYoungtoRun: Gbájú-ẹ̀ ni Saraki lò fún wa

Aworan Bukola Saraki

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki

Àkọlé àwòrán, Sẹnẹtọ Bukola Saraki wa lara awọn ọmọ ẹgbẹ PDP to kede lati du ipo Aarẹ orileede Naijiria
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ẹgbẹ ọdọ tó pé ará wọn ni ''Not Too Young to Run Movement'' ti bẹnu àtẹ lù bí Ààrẹ ile aṣòfin àgbà Nàìjíríà Bukola Saraki ti ṣe fi ayẹyẹ wọn kéde pé òun fẹ dupo ààrẹ.

Won ni ọtọ ní nnkán tí àwọn pé Saraki wá ṣé kí o tó ṣadede fi ayẹyẹ àwọn kéde èrò rẹ láti dije ipò Ààrẹ Nàìjíríà.

Lọjọbọ ni ẹgbẹ náà fi ọrọ yí síta lójú òpó Twitter wọn lẹyìn tí fónrán fídíò kan se àfihàn àwọn ọdọ tó n dunu níbi ayẹyẹ wọn ti Saraki ti kéde pé òun yóò dije ipò Ààrẹ Nàìjíríà

Ninu atejade naa, ẹgbẹ náà ni ojú gbà awon tí fún Saraki pẹlú bí ọ ti ṣe wù iru wa bẹẹ.

Atejade ẹgbẹ Not Too Young to Run Movement

Oríṣun àwòrán, @YIAGA

Àkọlé àwòrán, Sadede ni Saraki fi ayẹyẹ wa kéde èro rẹ láti dije ipò Ààrẹ Nàìjíríà.

Bakan naa ni wọn tẹsíwájú pé àwọn kò gbé lẹyìn Saraki tàbí ni ero lati kopa gẹgẹ bi ẹgbẹ oselu.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ọrọ kò rí bẹẹ

Nínú èsì rẹ sí ọrọ àwọn ẹgbẹ ọdọ náà,Senator Bukola Saraki ti agbẹnusọ rẹ Yusuph Olaniyonu fi atẹjade síta lórúkọ rẹ sọ pé òun ṣe ìkéde náà láti ṣe ìwúrí fún àwọn ọdọ ẹgbẹ òṣèlú PDP ton n gbero láti du ipò ní.

''Lootọ ni pé àwọn ọdọ ẹgbẹ náà kò mọ sí èrò mí ṣùgbọ́n mi o gbèrò láti ṣe àkóbá fún wọn.

O ni ''mo mọ riri ipa ti awọn ọdọ nkọ lorílè-èdè yí, má sì má tẹsiwaju láti má b'awọn ṣíṣe pọ''