Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto fẹ́ dupò Ààrẹ

Tambuwal
Àkọlé àwòrán, Tambuwal

Aminu Tambuwal, gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto ti gbà ìwé ìyanisípò ààrẹ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP).

Olóṣèlú yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ kúrò ní ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) lọ sí ẹgbẹ́ PDP ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí.

Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́rú ni Tambuwal pẹ̀lú àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ ya wọ olú ilé iṣẹ́ ẹgbẹ́ alátakò náà, Wadata Plaza ní ìlú Abuja.

Ó sọ fún àwọn oníròyìn wí pé ó dá òun lójú wí pé àwọn adarí ẹgbẹ́ yóò ṣe ìdìbò abẹ́nú tó yanrantí bí àwọn olùdíje kò bá fẹnu kò lórí olìdíje kan ṣoṣo.

Bukola Saraki fẹ́ rẹ ọmọ Nàìjíríà lẹ̀kún ní 2019

Ààrẹ ilé ìgbìmọ aṣofin Bukola Saraki ti fí èròńgbà rẹ̀ hàn láti dupò ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà níbi ìdìbò gbogboogbo lọ́dún 2019.

Bukola Saraki àti àwọn ero

Oríṣun àwòrán, Saraki/twitter

Àkọlé àwòrán, Bukọla Saraki fi èrọngbà han lati di ààrẹ Nàìjíríà

O sọ èyí di mímọ lónìí lásìkò tó kàwé àpilẹ̀kọ rẹ̀ níbi ìpàdé pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ tó ń gbèrò láti dúpò ààrẹ lọ́dún tó ń bọ.

Ó ní ' mo fí àsìkò yìí fí èrò ọ̀kàn mi hàn láti díje fún ipò ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà níbi ìdìbò gbogboogbò ọdún tó ń bọ lábẹ́ àsíà People's Democratic Party (PDP). mó ṣe èyí pẹ̀lú àrídájú pé ǹ ó mú ìdàgbàsókè bá orílẹ̀-èdè yìí àti àwọn ènìyàn rẹ̀.'

Bukola Saraki

Oríṣun àwòrán, Saraki/twitter

Àkọlé àwòrán, Bukola Saraki 2019: Mo fẹ́ rẹ ọmọ Nàìjíríà lẹ̀kún ní

Ètò ọrọ̀ ajá wa ti dẹ́nu kọlẹ̀ tán èyí sì nílò àtúnṣe ní kíákíá kí orílẹ̀-èdè yìí baa lè ni ìdàgbàsókè., Saraki ni ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ kò rí iṣẹ́, oko-òwò ti di gbígbé ti sps àwọn ènìyàn míràn sì ń pàdánù iṣẹ́ wọn lójoojúmọ.

Ààrẹ̀ ilé ìgbìmọ aṣofin àgbà tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé pàtàkì ìdí ti òun fi fẹ́ díje ni lati láti dá ògò orílẹ̀-èdè yìí pada nítori ìpinyà ti wàà láàrín àwọn ẹlẹ́yà -mẹ̀yà, láàrin ẹkún kọ̀ọ̀kan, ẹsìn àti ìbáṣepọ̀.

Saraki ní òun fẹ́ ki àwọn ọ̀dọ́ máa kó ipa to lààmì-laaka láwùjọ nítori náà ìjọba oun yóò rii dájú pé ààyè to tọ ni wọn yóò wà.