Nàìjíríà kéde orúkọ àwọn agbábọ́ọ̀lù Falconets fún ìdíje àgbáyé

Oríṣun àwòrán, FIFA.com
Olukọni fun ikọ agbabọọlu ọdọbinrin orilẹede Naijiria ti ọjọ ori wọn ko ju ogun ọdun lọ, Christopher Danjuma ti kede orukọ awọn agbabọọlu mọkanlelogun ti yoo ṣoju naijiria nibi idije ife ẹyẹ agbaye awọn ọdọbinrin ti ọjọ ori wọn ko ju ogun ọdun lọ, FIFA U20.
Ikọ Falconets kii ṣe ajeji si idije ife ẹyẹ agbaye, ṣugbọn ikọ yii ko tii fi igba kan pa idije yii jẹ lati igba ti o ti bẹrẹ.
Idije naa yoo waye laarin ọjọ karun si ikẹrinlelogun oṣu kẹjọ ni orilẹede france.


Orilẹede Naijiria, Brazil, Germany ati Amẹrika nikan ni orilẹede mẹrin ti ko tii figbakan ri jẹ awati nibi ọdọbinrin ti ọjọ ori wọn ko ju ogun ọdun lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Igba meji ni orilẹede naijiria ti de ipele aṣekagba; orilẹede Germany lo si na wọn ni igba mejeeji ni ọdun 2010 ati 2014.
Ireti ọpọ si ni pe ikọ Falconets yoo lee gba ife naa lọdun yii lẹyin ti awọn agbabọọlu ọkunrin, Super eagles ti ja ireti ọpọ ọmọ Naijiria kulẹ lorilẹede Russia nibi idije ife ẹyẹ agbaye Russia 2018.













