Ìkọlù UK: Agbébọn pa ọmọ asòfin àpapọ̀ Nàíjíríà kan

Abraham Badru

Oríṣun àwòrán, Facebook/ Dolapo Badru

Àkọlé àwòrán, Abraham Badru ni ọmọ kansoso tí ìyá rẹ̀ bí

Àwọn agbébọn ti pa ọ̀dọ́kùnrin kan, Abraham Badru, ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, tíí se ọmọ Asòfin Dọlápọ̀ Badru, tó ń sojú ẹkùn ìdìbò erékùsù ìpínlẹ̀ Èkó ní ilé asojú sòfin ní Àbújá.

Abraham, tó ń sisẹ́ gẹ́gẹ́ bíi Olùkọ́ni lérée bọ́ọ̀lù lẹ́yìn tó gba oyè kún oyè nílé ẹ̀kọ́ fásitì Gloucestershire ní ìlú ọba ni wọ́n sekúpa ní ìlú London lọ́jọ́ Àìkú.

Aláìsí náà, tíí se ọmọ kan soso tí ìyá rẹ̀ bí, ni àwọn kan sádédé yìnbọn fún níwájú ilé ìyá rẹ̀ lásìkò tó ń bọ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ rẹ̀, èyí tó mú kí ìyá rẹ̀ sáré jáde síta, tó sì di òkú ọmọ rẹ̀ mọ́ àyà.

A gbọ́ pé Abraham,ni èèyàn kẹwàá tí wọn yóò yìnbọn pa ní ìlú London ní ààrin ọ̀sẹ̀ méjì.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amin iyasọtọ kan

Nígbà tó ń sàlàyé ikú tó pa ọmọ rẹ̀, Asòfin Badru ní, ọmọ òun kò rin ìrìnkurìn nítorí ọ̀dọ̀ òun ló ti kúrò ní aago mẹ́sàn án alẹ́ ọjọ́ náà, tí àwọn méjéèjì sì jíròrò nípa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ tó fẹ́ dẹnu ìgbeyàwó kọ eyí tó kí àwọn fi se awo.

''Ikú Abraham dùnmí jọjọ"

Baba Abraham, Asòfin Badru ní, "ọmọ jẹ́ẹ́jẹ́, tó gbọ́ràn ni Abraham, tí kìí se ojo. Kódà ó kojú àwọn jàǹdùkú kan tó fẹ́ fi tipátipá bá obìnrin kan lòpọ̀.''

Fẹ́mi Gbàjàbíàmíà, olórí ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú tọ pọ̀ jùlọ nílé asojú sòfin ilẹ̀ wa, nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta ní Àbújá rọ àwọn asòfin yòókù láti tu mọ̀lẹ́bí náà nínú.