Venezuela; Orílẹ̀-èdè Columbia àti Amerika lò wá nídì àdó olóró
Ikú agbanipa kò yọ Aarẹ Nicolás Maduro silẹ ni Venezuela.
Ọrọ di boolọ koo ya a mi ni orilẹ-ede Venezuela lasiko ti ori yọ Aarẹ ile naa, Nicolás Maduro, nigba ti awọn onise ibi kan gbiyanju lati pa a pẹlu ado oloro.
Aarẹ Maduro n sọrọ nibi ayẹyẹ ayajọ awọn ologun ilẹ naa ni Caracas to jẹ olu ilu orilẹ-ede Venezuela.
Minisita fun ọrọ iroyin ni ilẹ naa, Jorge Rodriguez, fi sita wi pe ọkọ ofurufu kekere meji to n wa ara rẹ kun fun ado oloro bu gbamu ni ẹgbẹ ibi ti Aarẹ Maduro duro si.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Fonran ti wọn fi jade fihan pe aarẹ naa n sọrọ lọwọ ni o tete gbe oju soke pẹlu ẹru, ti awọn ologun si bẹrẹ si ni sare nigba ti ọkọ ofurufu kekere to n wa ara rẹ naa n ṣe efin ni oke.
Aarẹ Maduro ni isẹlẹ naa ko sẹyin Colombia ati awọn oluranlọwọ wọn lati ilẹ Amerika, eleyi ti Aarẹ ilẹ Columbia sọ wi pe irọ lasan ti ko si ootọ ninu rẹ ni.
Awọn alasẹ ilẹ Venezuela fikun pe awọn ologun meje ni o faragba ninu isẹlẹ naa, ti wọn si fi panpẹ ọba mu awọn afurasi nibi isẹlẹ naa.












