WBC title: Deontay Wilder lu Dominic Breazeale bí ẹni lu bàrà láti di ìgbánú ẹ̀yẹ WBC mú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Afẹsẹkubiojo Deontay Wilder ti fi ayo kun inu awọn ololufẹ rẹ, lẹyin to di igbaju igbamu bo Dominic Breazeale lati di Ife Ẹyẹ WBC World Heavyweight mu digba digba ni ilu New York lorilẹede Amerika.
Wilder to jẹ ọmọ ọdun mẹtalelọgbọn lo ba ọmọ ilẹ Amerika ẹgbẹ rẹ,Dominic Breazeale ja.
Wilder to fakọyọ ninu ija naa,ti gbe igba oroke ni igba mọkanlelogoji ninu fi fi ẹsẹkubiojo. nise ni Breazeale sun gbalaja silẹ ti ko si le e dide si pipe ago, eleyii to mu Wilder bori ninu ija naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Amọ, Wilder yoo koju ipẹjọ Ajọ to n risi ere idaraya ifẹsẹkubiojo nitori o sọ wi pe gbagede ifẹsẹkubiojo nikan ni eniyan ti le paniyan, ti a si lo ni idare.








