FIFAWWC: Ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ Germany ati Naijiria ti parí pẹ̀lú àmi ayò ìbànújẹ́ mẹ́ta

Oríṣun àwòrán, Fifa Women World Cup/Twitter
Ikọ Germany ati Super Falcons Naijiria wako ni France ninu idije ife ẹyẹ agbaye ti awọn obinrin to n lọ lọwọ ni ọjọ Abamẹta, ṣugbọn lẹyin ò rẹyin, Germany fi agba han Naijiria pẹlu ami ayo mẹta si odo.
Lẹyin ogun iṣeju, ikọ Germany fun Naijiria ni ami ayo kan. Ṣugbọn iṣeju marun lẹyin rẹ, wọn tun fun wọn ni wo-mi-n-gba-si-ọ, to sọ ami ayo naa di meji.

Oríṣun àwòrán, Germany/Twitter
Pẹlú iṣẹju mẹjọ si ipari ifẹsẹwọnsẹ naa, wọn tun ti fi ikẹta lee.

Bayii ipele ko mẹsẹ o yọ ni idije ife ẹyẹ agbaye awọn obinrin FIFA de duro.
Orilẹ-ede Germany lo ṣaaju ninu ẹgbẹ B nitori wọn bori ninu idije mẹta wọn nigba ti Naijiria bori ninu idije kan to sọ wọn di alaṣeyọri kẹta ni ẹgbẹ A.
Igba akọkọ laarin ogun ọdun ni yii, ti Naijiria a de ipele ikẹrindinlogun ninu idije ife ẹyẹ agbayeSuper Falcons gòkè odò bọ́ sípele ìkẹrìndínlógún ní France.
Agbabọọlu Naijiria ni ikejidinlogoji to dara julọ ni agbaye.
Lara awọn to maa gba bọọlu fun Naijiria ni Osinachi Ohale, Onome Obi, Rita Chikwelu, Francisca, Desire Oparanozie atawọn mii.
Asisat Oshoala ni yoo ṣaaju awọn ẹlẹsẹ ayo ninu idije naa.
Ta ni Germany ti Naijiria n koju?
Awọn agbabọọlu orilẹ-ede Germany ni ikeji to dara julọ ni gbogbo agbaye.
Germany lo gbalejo idije ife ẹyẹ agbaye lọdun 2011.
Awọn ni wọn bori ninu idije wọn pẹlu orilẹ-ede USA to dara julọ ni agbaye lọdun 2011.
Awọn agbabọọlu mẹfa lo ku ninu awọn mejidinlọgbọn ti wọn ṣoju orilẹ-ede wọn nigba naa.
Alexandra Popp lo ku ninu awọn agbabọọlu naa to maa koju Naijiria.
Alexandra yoo gba bọọlu fun igba ọgọrun un ti Germany ba koju Naijiria loni.
Orilẹ-ede Germany ti gba ife ẹyẹ agbaye tawọn obinrin lọdun 2003 ati 2007.

Oríṣun àwòrán, others
Nigba ti wọn gbe ipo keji ni ọdun 1995.
Ipo kẹrin ni Germany gbe lọdun 1991 ati 2015.
Ileri Super Falcons fun awọn ọmọ Naijiria:
Nitootọ ni ọpọ gba pe Germany kii ṣe ẹran rirọ fun Naijiria ṣugbọn awọn agbabọọlu Naijiria ni awọn a gbiyanju lati bori.
Onome Ebi, ọkan lara awọn agbabọọlu ti oju wa lara rẹ ni awọn sa ipa awọn ninu idije pẹlu France ko to di pe wọn gba ami ayo kan sile Naijiria ninu kọju si mi koo gbaa sile.
O ni Naijiria ko wa ta guguru ni France, a maa bọ si ipele to kan lagbara Olorun ni.
















