World Cup 2018: Senegal fẹ̀yin Poland gb'ólẹ̀ ní Russia

Saido Mane

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ikọ̀ Senegal na orílẹ́èdè France nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé ọdún 2002

Lẹyin ti awọn orilẹede mẹrin lati ilẹ Afirika ti fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ wọn, Senegal yoo koju Poland lọjọ Iṣẹgun ninu 2018 Russia World Cup.

Egypt, Morocco, Nigeria ati Tunisia lo fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ wọn ninu idije ife ẹyẹ agbaye to n lọ lọwọ.

Ẹwẹ, bi ikọ Senegal ti n mura lati koju orilẹede Poland nilu Moscow, akọnimọọgba ikọ naa Aliou Cisse ti ṣapejuwe Saido Mane bi agbabọọlu to dara ju lọ.

Cisse sọ pe Mane to n gba bọọlu fun ikọ Liverpool yoo ran orilẹede Senegal lọwọ nigbati wọn ba koju Poland.

Cisse ni balogun ẹgbẹ agbabọọlu Senegal ti wọn na orilẹede France ni 2002 World Cup ti wọn si de ipele kẹta ninu idije naa.

Ninu awọn idije miran ti yoo waye lọjọ Iṣẹgun, Russia yoo waako pẹlu Egypt ninu ifẹsẹwọnsẹ keji wọn bi Colombia ati Japan yoo ṣe gbena woju ara wọn.