Liverpool yóò koju Real Madrid ni aṣekagba Champions league

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ikùn imú t'ọtun fẹẹ bó sí tosí fún Liverpool ki wọn tó lè tèsíwájú sí aṣekagba ìdíje Champions League.
Nínú Ifesewonse tó wáyé láàrin àwọn àti Roma ni Stadio Olimpico ni Rome, àpapọ góòlù méje sí mẹfa ni Liverpool fi pegede.
Èyí ni ìgbà àkọkọ tí Liverpool yóò kópa nínú aṣekagba Champions League láti ọdún 2007.
Akoni-moogba ẹgbẹ náà Jurgen Klopp gbe osuba kare fún àwọn ikọ rẹ àti àwọn alatilẹyin ẹgbẹ náà.
Ayo máàrún sí méjì ni wọn gbà ní abala kíni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn ni Anfield.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìpàdé yí ti Roma na wọn pẹlú ayo mẹ́rin sí méjì ní àkókò ifidiremi won nínú ìdíje Champions League.
Ṣugbọn eléyìí ko le ṣe idiwọ fún wọn láti kópa nínú aṣekagba ti yóò wáyé ni pápá iṣere NSC Olimpiyski lorílẹèdè Ukraine ni ọjo kejidinlọgbọn Oṣù Kàrún, ọdún 2018.
Liverpool àti Real Madrid ni yóò jọ wàá kò.












