Bayern Munich kò ní gbọ́; Real Madrid kò ní gbà lálẹ́ òní

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lálá yóò lù lálẹ́ òní, Ọjọ́rú nínú ìdíje UCL.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni'gbà tí ẹgbẹ́ agbábọ́òlù Bayern Munich àti Real Madrid yóò kojú ara wọn nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tó kángun sí àṣekágbá ìdíje UCL tó ń lọ lọ́wọ́ ni Yúròòpù.
Bẹ́ẹ̀ ọ̀rọ̀ bọ́ọ̀lù kò ṣee fi ojú di.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Èrò onímọ̀ nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀
Ogbeni Tijani Adewale ni: Kò sí ẹni tí kò lè lu ara wọn lálẹ́ òní nínú àwọn méjèèjì.
Ṣùgbọ́n, Ó ṣeéṣe kí Real Madrid fàgbàhan Bayern Munich nítorí pé wọ́n ti nà wọ́n nílé àti níta tẹ́lẹ̀.
Bákan náà ni wọn ti nà Bayern Munich ní ẹ̀ẹ̀maruǹ uń tí wọn pàdé sẹ́yìn.
Ìran ni oúnjẹ ojú, Ronaldo ati Lewandowski yóò wọ̀yá ìjà láìpẹ́









