Ikọlù Benue: Adaran pa àlùfáà méjì, ọmọ ìjọ 13 ní ilé ìjọsìn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìròyìn tí ó ńkàn sí wa fihàn wípé àwọn darandaran agbébọn ti pa àlùfáà méjì àti ọmọ ìjọ mẹ́tàlá ní ilé ìjọsìn kátólíkì kan tí ó wà ní Ayar Mbalom ní ìjọba ìbílẹ̀ ìlà oòrùn Gwer ní ìpínlẹ̀ Benue.
Àwọn darandaran náà ni a gbọ́ pé ó ṣe àkọlù náà sí St. Ignatius Quasi Parish, Ukpor-Mbalom ní bíi aago mẹ́fà àárọ̀ ọjọ́ ìṣẹ́gun nígbà tí àwọn olùjọ́sìn ìjọ náà lọ sí ìjọ́sìn àárọ̀.
Terver Akase ti ó jẹ́ agbẹnusọ fún Gomina Samuel Ortom sọ fún BBC pé awon fada ti o padanu emi won ninu akolu naa ni Fada Joseph Gor ati Fada Felix Tyolaha.
Akase so wípé lẹ́hìn tí àwọn darandaran náà ṣọṣẹ́ tán ní ilé ìjọsìn náà, wọ́n tún sọ'ná sí ilé bíi àádọ́ta ní ìlú náà kí wọn tó sa lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ ènìyàn ni ó ti kú ní Benue láti 2013
Oṣù kejì ọdún yìí ni kọmíṣọ́nnà fún ìbánisọ̀rọ̀ àti ìlanilọ́yẹ ní Benue, Lawrence Onoja, sọ wí pé bíì ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ ènìyàn ni ó ti kú ní Benue láti 2013 nínú ìkọlù àwọn darandaran agbébọn, tí ogunlọ́gọ̀ sì pàdánù dúkìá, ohun ọ̀gbìn àti ilé wọn.
Ẹ ó rántí wípé ní oṣù kínní ọdún yìí ni ìjọba ìpínlẹ̀ Benue sin òkú métàléláàdọrin tí àwọn agbébọn pa.









