Olùdásílẹ̀ Wikileaks gba òmìnira kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn ọdún márùn-ún

Aworan Julian Assange lẹyin ọpọ ọdun ni ahamọ

Oríṣun àwòrán, PA Media

Si awọn alatilẹyin rẹ, Juilan Assange ni olupolongo otitọ. Si awọn alatako rẹ, o jẹ eeyan kan to n se karimi, to si n ko ọpọ eeyan sinu wahala pẹlu bi o se n fi awọn iroyin kan sita.

Assange ni awọn to n ba sisẹ sapaejuwe gẹgẹ bii eeyan to ni oye, to si wọle inu ẹrọ ayarabi asa bi o ṣe wu.

O da Wikileaks silẹ, ileeṣẹ to n gbe awọn iroyin ati aworan sita, ni ọdun 2006, o hanb ni gbogbo awọn iwe iroyin kaakiri agbaye nigba to fi fọnran bi awọn ọmọ ologun Usse yinbọn lu awọn araalu Iraq lati ori baalu..

Lọdun naa, Assange, ẹni to wa lati Australia dero ahamọ ni Ilẹ UK, ti wọn si pada gba beeli rẹ lẹyin ti orilẹede Sweden fẹsun kan pe o fipaba eeyan kan lopọ.

Assange ni awọn eeyan kan to sisẹ pe ki wọn gbe oun lọ si ilẹ US lati lọ koju awọn ẹsun kan-

Nigba ti Assange ti gba ominira – wọn gba baali rẹ, to si wa lọna si Ariwa Mariana islands nibi ti gbagbọ wa pe o baalẹ si ọjọru lati sọ pe oun jẹbi ẹsun naa to ti wa fun ọdun mẹrinla, to si n lọ kiri orilẹede marun un.lẹyin to tọwọ adehun pẹlu ijọba US

Igbagbọ wa pe wọn yoo fi silẹ ni ẹsẹkẹsẹ , nitori akoko to ti lo ni ahamọ ni ilẹ UK, ti yoo si pada si Australia.

Bi nnkan ṣe bẹrẹ

Assange lọra ni gbogbogbo lati sọrọ nipa ibẹrẹ rẹ, ṣugbọn iwulo ayelujara lati igba ti Wikileaks ti jade ti tan imọlẹ si awọn ipa rẹ.

Wọn bi ni Townsville ni ilu Australia ni Queensland ni ọdun 1971, awọn obi rẹ n mu awọn eeyan irin ajo ere itage. O di baba ni ọdun mọkandinlogun ti awọn ogun ibo ni ọmọ yoo wa tẹle.

Idagbasoke opo ayelujara fun un ni aye lati lo ileri akọkọ rẹ nidi iṣiro, botilẹjẹpe eyi paapaa yori si awọn iṣoro

Aworan Assange

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ni ọdun 1995 ti fi ẹsun kan Assange, pẹlu ọrẹ kan, pe wọn lo ọna eburu lati wọle si awọn ẹrọ ayarabi asa. Botilẹjẹpe ẹgbẹ yii jẹ ti iṣẹ ye pupọ lati mọ pe awọn agbofinro kan gbiyanju lati wa wọn ri, wọn ri Assange mu, to si gba pe o jẹbi.

O san owo itanran ọpọlọpọ ẹgbẹrun dọla Australian - lati ma jẹ ko lọ si ẹwọn lori majemu wipe o ko ni ṣe iru nnkan bẹ mọ.

O bọ si ẹka ẹkọ kika – to si kọ iwe to dara julọ lori ihalẹ ti intanẹẹti saaju ko to lọ mọ nipa imọ fisisi ati mati.

Iṣẹ Wikileaks

Assange bẹrẹ Wikileaks ni ọdun 2006 pẹlu ẹgbẹ awọn eeyan to da bi rẹ kaakiri ori wẹẹbu, ṣiṣẹda “Dead-letterbox” fun awọn eeyan to fẹ ma tu asisri.

“[Lati] jẹ ki awọn orisun wa ni aabo, a ni lati tan kaakiri awọn ohun-ini, fifipamọ ohun gbogbo, ati gbe awọn ibaraẹnisọrọ ati awọn eniyan kakiri agbaye lati mu awọn ofin aabo ṣiṣẹ ni awọn sakani orilẹ-ede oriṣiriṣi,” o sọ fun BBC ni ọdun 2011.

“A ti dara nibẹ, ati pe a ko padanu igbẹjọ kan, tabi orisun kan, ṣugbọn a ko le nireti pe gbogbo eniyan yoo lọ nipasẹ awọn ipa iyalẹnu ti a ṣe.”

Aworan Assange pẹlu BBC

Lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti wọn ti n fa igbẹjọ yii, Ileeṣẹ Wikileaks ni oludasilẹ wọn, Julian Assange ti kuro ni Ilẹ UK lẹyin adehun ko pẹlu ijọba US ti yoo ri pe o gbe pe o jẹbi ẹsun ọdaran ti wọn fi kan, ti yoo si ma lọ.

Assange, ẹni ọdun mejilelaadọta , ni wọn fi ẹsun pe o lo ọna eburu lati mọ nipa awọn iroyin nipoa aabo ilu.

Fun ọpọlọpọ ọdun, Ijọba US ni awọn iroyin to wa lọwọ Wikileaks, kede awọn iroyin kan nipa ogun Iraq ati Afghanistan, to si dunkoko mọ ẹmi awọn eeyan.

O lo ọdun marun un ni ọgba ẹwọn ilẹ Gẹẹsi, nibi to ti n koju igbẹjọ lori bi wọn se gbe pada si ilẹ US.

Bakan naa ni Assange tun n koju awọn ẹsun mi bii ifipabanilopọ ni orilẹede Sweden, ti to ni oun ko mọ nipa rara.