Kyari ní òun yóò fún mi ní mílíọ̀nù 10 àti físà lọ orílẹ̀-èdè tó bá wùmí tí n bá lè ṣé àkóbá fún Saraki- Afurasi 

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Ọkan lara awọn afurasi to n jẹjọ lori idigunjale to waye ni Offa, nipinlẹ Kwara, Ayoade Akinrinbosun tí tu kẹkẹ ọrọ nile ẹjọ.

O sọrọ lori bí Ọga agba fun ẹka ileeṣẹ ọlọpaa IRT tẹlẹ, DCP Abba Kyari ṣe fi miliọnu mẹwaa naira lọ oun lati ṣe akoba fun Gomina tẹlẹ ni Ipinlẹ Kwara, Bukola Saraki lori idigunjale náà.

Afurasi naa, nigba to n sọrọ niwaju Adajo Alimat Salam, ni ileẹjọ giga ipinle Kwara ni ẹni to lewaju idigunjale naa Michael Adikwe, ẹni tí wọn yinbọn lu ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ni Abuja Abbatoir.

O ni iṣẹlẹ naa lo jẹ ki oun gba lati se akoba fun Bukola Saraki ninu atẹjade tí wọn fi ransẹ si awọn akọroyin.

Ayoade, to jẹ ọkan lara awọn afurasi marun un to n jẹjọ lori idigunjale to waye ni Offa.

Bakan ni Agbẹjọro, Mathias Emeribe ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn afurasi fi idi rẹ mulẹ pe Abba Kyari ṣeleri fun adigunjale pe wọn yoo ni anfani sì fisa Orilẹede to ba wu wọn ti wọn ṣe akoba fun Saraki.

Ayoade tẹsiwaju pe oun ko gbọ sì Kyari lẹnu pe ki oun sọ fun awọn ọmọ Orilẹede Naijiria pe Bukola Saraki lo ran awọn ni isẹ lati lọjale.

"Mo sọ fun pe n ko ni lese ati pe maa yaku ni ju kí n parọ mọ eeyan ti ko mọwọ mọ ẹsẹ."

O ni Abba Kyari ni kí oun lọ ro dada, to si ni kí Hassan and Mashood da oun pada si inu atimọle to yatọ si ti awọn yoku ati pe wọn ko gbọdọ na oun mọ.

Saraki ko mọ ohunkohun nípa idigunjale naa - Ayoade

Ayoade ni lẹyin ti oun kuna lati ṣe ohun ti wọn beere fun, ni wọn bẹrẹ si ni maa fiya jẹ oun, tí wọn si tun yinbọn lu oun lẹsẹ.

Afurasi naa ni Bukola Saraki ko mọ ohunkonu nípa idigunjale naa rara.

" A to mẹẹdogun sì ogun afurasí tí wọn ko lọ sí Abuja.

Mo mọ diẹ lara wọn.

A wa nita, ti wọn si fun ni oúnjẹ sugbọn n ko le jẹ nítorí bi wọn ṣe tí lumi niluu Ilorin,

mo wa ni kí Kunle Ogunleye fi ọwọ rẹ fun mi ni oúnjẹ naa."

Adajọ tí wa sun Igbẹjọ naa siwaju di ọjọ kẹtala, oṣu kejì ọdun 2023