Ọwọ́ tẹ afurasí olè tó n jí orúkọ àwọn òkú ní ibojì

Oríṣun àwòrán, MAHER MEZAHI

Oríṣun àwòrán, KANO STATE POLICE COMMAND
Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Kano kede pe ọwọ oun ti tẹ arakunrin ẹni ọdun mọkandinlogun kan to kundun lati ma a yọ awọn irin pẹlẹbẹ ti wọn kọ orukọ ati ọjọ iku awọn oku si ni iboji.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa Kano, SP Abdullahi Kiyawa, sọ pe irin mejidinlọgbọn ni wọn ri gba lọwọ afurai naa lẹyin to ko wọn ni ilẹ isinku Tudun Wada niluu Kano.
Afurasi naa ni wọn ni o jẹwọ fun awọn ọlọpaa pe, aago mẹta oru ni oun ma n lọ si ilẹ isinku lati jí awọn irin naa.
O ni oun ma n ta awọn irin naa fun awọn alagbẹdẹ to n fi wọn rọ awọn nnkan miran.
Iroyin sọ pe N300 lo ma n ta kilogiramu irin kan.
SP Kiyawa sọ pe awọn yoo gbe e lọ sile ẹjọ, ni kete ti iwadii ba pari lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Oríṣun àwòrán, KANO STATE POLICE COMMAND
Oṣiṣẹ kan ni ilẹ isinku, Magaji Adamu, to ti n ṣiṣẹ lati ọdun naa fun ọdun marundinlọgbọn sọ pe iru nnkan bayii ko jẹ tuntun.
O ni ọwọ ti tẹ iru ole bẹẹ ni igba meji, ni ilẹ isinku ti oun ti n ṣiṣẹ lasiko ti wọn wa yọ awọn irin pẹlẹbẹ ti wọn kọ orukọ ati ọjọ iku awọn oku si.
“Koda, ile ẹjọ ran ole ti a kọkọ mu lọ si ẹwọn fun ọdun meji.”
Arakunrin Adamu sọ pe iwa arinfin ati ẹgbin ni iru nnkan bayii jẹ si awọn oku, ati fun ilẹ isinku to yẹ ko jẹ ibi isinmi fun awọn ara to ti fi aye yii silẹ.














