‘Ọmọ 263 ni àwọn ìyàwó Boko Haram tó ronúpìwà bí láàrín oṣù mẹ́rin’

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ijọba ipinlẹ Borno ti kede pe awọn iyawo ikọ Boko Haram to ronupiwada ti bi iye ọmọ to le ni igba ati ọgọta laarin oṣu mẹrin.

Ijọba sọ eyi lasiko ti wọn n ba awọn oniroyin sọrọ ni Maiduguri.

Awọn ọmọ ti wọn bi naa wa ni ileewosan to wa ninu agbegbe ogunlende Hajj, ni ilu Maiduguri.

Ijọba ni agbegbe yii ni wọn n lo gẹgẹ bi ile igbe fun awọn ikọ Boko Haram to ba ronupiwada.

Ojoojumọ la n gbẹbi ọmọ ni Hajj Camp - Dokita

Gẹgẹ bi ọrọ ti ijọba sọ, o kere tan ẹgbẹrun mẹrindinlogun ni awọn ikọ Boko Haram to ronupiwada to wa ni ikawọ wọn.

Lasiko ti wọn n fi alakalẹ naa han fun awọn oniroyin, dokita Mohammed Saleh ni awọn ọmọ mẹrinlelaadọrun ni wọn bi ni Oṣu Kẹjọ, Oṣu Keje, ti wọn si bi ọgọta ni Oṣu Kẹta ati mọkanla ni osu kẹwaa.

Dokita Mohammed ni ko si ọjọ kan ti awọn eniyan kii bimọ ninu ileegbe naa.

Bakan naa lo fikun un pe ẹẹdẹgbẹta obinrin lo ṣi wa ninu oyun lọwọlọwọ.

Ijọba Borno ni awọn ikọ Boko Haram to ronupiwada naa ti wa ni ikawọ ijọba ni ilu Maiduguri.