Àgbà òṣèlú Edwin Clark ti jáde láyé ẹ̀ẹ́ni ọdún 97

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Aṣiwaju ajọ agbarijọpọ ẹgbẹ ọmọbibi ẹkun Niger Delta, PANDEF lorilẹede Naijiria, Alagba Edwin Clark ti jade laye.
Kan lara awọn aṣoju ẹbi rẹ, Ọjọgbọn C.C. Clark lo kede iku agba oṣelu naa.
Ọjọgbọn Clark kede iku Oloye Edwin Clark lọjọ Iṣẹgun.
O ni ọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlogun oṣu keji ni Oloye Clark jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgọrun.
"Idile Clark-Fuludu Bekederemo ni ilu Kiagbodo ni ipinlẹ Delta kede ipapoda Oloye (Ọmọwe) Sẹnetọ Edwin Kiagbodo Clark OFR, CON ni ọjọ Aje ọjọ kẹtadinlogun oṣu keji ọdun 2025.
Ẹbi yii mọ riri adura yin lasiko yii. Ẹbi yoo kede awọn ilana gbogbo to ba yẹ to ba ya,"
Nigba aye rẹ, Alagba Edwin Clark fi igba kan ri jẹ kọmiṣọna fun iroyin ni ijọba apapọ orilẹede Naijiria.
Ẹkunrẹrẹ iroyin yii n bọ laipẹ.












