Mọ̀ sí i nípa oríṣi ààrùn Corona tuntun, XEC, tó ń tàn kálẹ̀ báyìí

Oríṣun àwòrán, Getty
Awọn eeyan ti bẹrẹ si i ni oriṣi arun Corona tuntun, eyi to ṣeeṣe ko tan kalẹ laipẹ, ko si di Corona atijọ to ti waye ri, gẹgẹ bi awọn onimọ sayẹnsi ṣe sọ.
Orilẹede Germany ni wọn ti kọkọ ri ẹ̀dà Corona tuntun yii, eyi ti wọn pe ni 'XEC variant', inu oṣu kẹfa lo si jẹ jade.
Oriṣi Corona naa ti wa ni UK, US, Denmark ati awọn orilẹede miran bẹẹ, gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe sọ loju opo X ta a mọ si Twitter tẹlẹ.
Wọn ni Corona tuntun yii ni awọn kinni kan to le jẹ ko tan kalẹ lasiko yii, bo tilẹ jẹ pe o yẹ ki apa awọn abẹrẹ ajẹsara to n dena rẹ le ka eyi to ba fẹẹ le ju ninu aruna naa.
Awọn akọṣẹmọṣẹ lo fidi eyi mulẹ.
Fun awọn to ṣeeṣe ki Corona da gunlẹ gidi, ajọ NHS ti pese ilana idena rẹ lọfẹẹ.
Nipa awọn abẹrẹ ajẹsara ti yoo dena itankalẹ yii, wọn ti ṣe wọn lọna ti yoo fi ba Corona asiko yii dọgba. Bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe ti XEC yii, nitori irufẹ tiẹ ti jade ṣaaju.
Ọjọgbọn Francois Balloux, Oludari ''Genetics Institute, University College, London,'' sọ fun BBC pe bo tilẹ jẹ pe Corona XEC yii le tete ran ju awọn Corona ti tẹlẹ lọ, sibẹ, o ni o yẹ ki apa abẹrẹ ajẹsara ṣi le ka a lati daabo bo awọn eeyan.
O ni o ṣee ṣe ko jẹ XEC yii ni yoo fẹrẹ pọ ju nigba ti yoo ba fi di asiko otutu .
Ṣe Corona tuntun yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í jà?
Eric Topol, Adari Scripps Research Translational Institute, ni California, sọ pe ẹya Corona XEC ṣẹṣẹ n bẹrẹ ni.
" Yoo gba to ọsẹ pupọ tabi oṣu diẹ ko too di pe yoo bẹrẹ si i ja gidi.
"O daju pe XEC yoo lo igba tiẹ.
"Oun ni Corona tuntun.
" Ṣugbọn yoo to ọpọlọpọ oṣu ko too bẹrẹ si i ja ni ti ọwọ lile."
Bayii ni Eric Topol ṣalaye fun ẹka iroyin LA Times.
Àwọn àpẹẹrẹ wo ni èèyàn yóò máa rí tó bá ní XEC ?
Awọn apẹẹrẹ ti Korona atijọ maa n mu dani bi otutu ati ofikin yoo pẹlu.
Awọn yooku ni:
- Ara gbigbona
- Ara riro
- Ko maa rẹ eeyan
- Ikọ hihu tabi ki ọna ọfun maa dun eeyan.
Ọpọ eeyan ti aarun Corona ba fọwọ ba maa n ni alaafia pada laarin ọsẹ kan, ṣugbọn o le ju pẹ ju bẹẹ lọ nigba miran.
Gẹgẹ bi Mike Honey, ọkunrin kan to maa n ṣe akọsilẹ bi ikọlu arun yii ṣe n lọ ṣe ṣalaye loju opo X rẹ, o ni arun XEC yii ti gbalẹ kan ni Denmark ati Germany.
Adinku to ti ba bi ayẹwo Corona ṣe maa n waye tẹlẹ ti jẹ ko ṣoro lati mọ bi arun naa ṣe ti gbode kan si bayii.
Gẹgẹ bi UK Health Security Agency ṣe wi, wọn ni o maa n ṣẹlẹ bẹẹ, pe ki awọn kokoro aifojuri yii pada kuro bi wọn ṣe wa tẹlẹ, ki wọn si di oriṣi miran.
Awọn èèyàn tí wọ́n lè gba abẹ́rẹ́ àjẹsára ọ̀fẹ́ fún àrùn náà ni:
- Awọn ti ọjọ ori wọn ti le ni mẹrinlelọgọta soke
- Awọn ti wọn n gbe nile igbatọju awọn agbalagba ati arugbo.
- Awọn ti ọmọ ti ọjọ ori wọn le loṣu mẹfa, ti wọn si wa nipo boya wọn yoo ku tabi wọn yoo ye nileewosan.
- Awọn kọọkan ninu awọn olutọju, awọn ti wọn n da oju kọ itọju yii taara fun NHS, awọn ile itọju ati awọn oṣiṣẹ alabojuto awujọ.
- Abẹrẹ ajẹsara taara fun otutu ati Korona yoo bẹrẹ loṣu kẹwaa, bo tilẹ jẹ pe o ṣee ṣe kawọn kan ri tiwọn gba ṣiwaju igba yẹn.














