Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Ṣe ẹ ti gbọ?
Ki lo tun ṣẹlẹ?
Pe Ileeṣẹ́ to n ri si ọrọ bẹntiro ni Naijiria, NNPCL ti gbe atẹ tuntun iye ti wọn yoo maa ta lita epo bẹntiro jade
Elo wa ni bayii?
N950 ni wọn ni awọn yoo maa ta ni ipinlẹ Eko ati agbegbe rẹ, ti wọn yoo si maa ta ni N960 ni ipinlẹ Oyo ati agbegbe rẹ
Awọn ipinlẹ yooku wa n kọ?
Kan soju opo bbcnews.com/Yoruba
Ajọ to n ri si onka ni Naijiria, NBS ni adinku ba ọwọngogo ninu oṣu Kẹjọ
NBS ni ida mejilọgbọn ni ọwọn gogo jẹ loṣu kẹjọ dipo ida mẹtalelọgbọn to jẹ loṣu keje
Amọ ọwọngogo ounjẹ lo ṣi wa ni ida mẹtadinlogoji to wa tẹlẹ
Njẹ aarẹ Amẹrika tẹlẹ ri, Donald Trump kọ ni a ba maa pe ni arikuyẹri?
Wo o, o to bẹẹ, ṣebi ori lo tun ko o yọ ninu ikọlu miiran lasiko to n gba gọọfu ni Florida
Ileeṣẹ́ aabo FBI ni ọwọ ti tẹ afurasi Ryan Routh to gbiyanju lati kọluu
Eyi to n waye lẹyin oṣu meji tẹnikan yinbọn Trump mọ lasiko ipolongo ibo



