Kí ló fa gbas-gbos láàrin Davido àti Wizkid lórí ayélujára?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọpọ oko ọrọ lori ayelujare ni Wizkid fi ya awọn ololufẹ rẹ lẹnu.

Ọjọ Aje ni Gbajugbaja olorin takasufe bẹrẹ si ni ma sọkọ ọrọ si awọn akẹgbẹ rẹ lagbo orin.

Ori itakun ayelujara X ni rogbodiyan naa ti waye lopin ọsẹ.

Wizkid ni o ni ọpọlọpọ nnkan ti oun fẹ sọ sita sugbọn o jẹ eeyan ti ko ki n fi bẹrẹ sọrọ, yala loju aye abi lori ayelujara.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Ọrọ akọkọ ti Wizkid kọkọ gbe sita ni, “Ni ojoojumọ ni mo ni nnkan to pọ lati sọ sugbọn ẹnu ko da.”

Sugbọn bi o ṣe ni ẹnu ko da ni o ṣe fi n bu ọpọ awọn akẹgbẹ laagbo orin.

Lati ori Don Jazzy Davido lo ti bẹrẹ to si kan sara si gbajugbaja wolli, Chukwunemeka Ohanaemere ti ọpọ mọ si Odumeje.

Wo nnkan to sọ.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Nigba to di owurọ ọjọ Aje, ọkunrin kan lori ayelujara X pe akiyesi Wizkid si awọn ọrọ ti Ladipoe, olorin takasufe mii sọ nipa rẹ.

Wizkid fesi pada pe oun ko ki n fesi pada eeyan to wa labẹ Influencer.

Ko pẹ ti ọrọ naa jade ni Gbajugbaja agbeorinlarugẹ, Don Jazzy kuro lori ila awọn to n tẹle Wizkid lori ayelujara.

Ọpọ eeyan lo ti bu ẹnu atẹlu ọrọ ti Wizkid sọ si Don Jazzy yii, ti wọn hu fọnran kan jade nibi ti Wizkid ti ni oun sun si ile Don Jazzy.

Titi di asiko yii Don Jazzy ko ti fesi kankan si ọrọ naa.

Bẹ mi bi Davido ṣe n bẹbẹ

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 3

Ko ki n ṣe tuntun pe ija wa laarin Wizkid ati Davido, to si ti bẹrẹ tipẹ.

Lati igba ti awọn mejeeji ti di ilumọka ni ija yii ti bẹrẹ bo ti lẹ jẹ pe Wizkid farahan ninu fọnran Davido kan laipẹ yii.

Lọdun 2017, awọn mejeeji fi opin si ija to wa laarin wọn si ti wọn si farahan si odo ere orin wọn.

Lọdun 2023, wọn kede pe awọn yoo jọ rin irin ere orin papọ sugbọn ko si nnkan to ti ẹyin bọ.

Ninu ohun ti Wizkid gbe sita ni fọnran kan nibi ti Davido ti kunlẹ to si n bẹbẹ.

Wizkid sọ fun awọn ololufẹ pe ki wọn bẹ oun bi Davido ṣe n bẹbẹ ti wọn ba fẹ ki oun gbe orin tuntun sita.