Ohun tuntun míì sẹ́yọ níbi ìgbẹ́jọ́ Ekweremadu lórí ẹ̀sùn láti yọ ẹ̀yà ara ènìyàn ní UK

Ike Ekweremadu

Oríṣun àwòrán, Others

Igbákejì ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí, Ike Ekweremadu ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kojú ìgbẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn pé ó fẹ́ yọ ẹ̀yà ara ọmọkùnrin kan ní ìlú London.

Ike Ekweremadu, ìyàwó rẹ̀ Beatrice Ekweremadu, ọmọ wọn, Sonia àti dókítà kan Obinna Obeta ni wọ́n ń kojú ẹ̀sùn ṣíṣe òwò ẹrú ìgbàlódé.

Ní ọjọ́ Ajé ni ìgbẹ́jọ́ lórí ẹjọ́ náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀sùn pé Ekweremadu san owó fún ẹnìkan tó ń ta ọjà ní Eko láti tẹ̀le lọ sí UK láti wá lọ fi kídìnrín rẹ̀ kalẹ̀ fún ọmọ wọn, Sonia tí àìsàn kídìnrín ń bá jà.

Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ̀sùn kàn náà ní àwọn kò jẹ̀bi ẹ̀sùn náà.

Nígbà tó ń bẹ̀rẹ̀ ẹjọ́ náà, ẹni tó ń fẹ̀sùn kàn Ekweremadu, Hugh Davies ní Ekweremadu ti fi ipò àti ọlá rẹ̀ kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ jọ.

Ó ní ara Sonia Ekweremadu le balẹ̀ tí wọ́n bá ṣe pàṣípààrọ̀ kídìnrín mìíràn fun dípò láti kàn fún ènìyàn ní owó láti fi fi kídìnrín rẹ̀ sílẹ̀, èyí tó ní ó lòdì sí òfin.

Davies ní ọ̀pọ̀ àwọn tó máa ń fi ẹ̀yà ara wọn sílẹ̀ láti fi gba owó tàbí nǹkan mìíràn ló jẹ́ àwọn tálákà àti àwọn tí kò rí ọwọ́ họrí láwùjọ.

Ẹ̀wọ̀n gbére ni ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ìfiniṣẹrú ìgbàlódé ní UK, tí fífi ẹ̀yà ara sílẹ̀ lọ́nà àìtọ́ sì ni ìjìyà ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta.

Ẹni tó ń ta ẹ̀yà fóònù ni Ekweremadu mú láti Nàìjíríà láti yọ kídìnrín ní UK

Beatrice àti Sonia Ekweremadu

Davies ṣàlàyé pé ọmọkùnrin tí Ekweremadu mú láti yọ kídìnrín rẹ̀ ló jẹ́ ẹni tó ń ta ẹ̀yà ara fóònù ní Eko.

Ó ní láti abúlé kan ni ọmọ náà ti wá, tí kò sì mọ ọjọ́ orí rẹ̀, tó kàn bu ọjọ́ orí kan láti lè fi hàn wí pé kìí ṣe ọmọdé.

Ó fi kun pé wọ́n ti ṣe àyẹ̀wò fún ọmọ náà láti Nàìjíríà láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé kídìnrín rẹ̀ àti Sonia bá ara wọn mu àti pé pọ́ùn 2,400 ni wọ́n jẹ́jẹ̀ẹ́ láti fún-un àti pé àwọn máa ba ṣé tí yóò máa gbé UK, tí yóò sì máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀.

Ó ní gbogbo ẹ̀jẹ́ yìí ni ló ràn mọ́ ọmọkùnrin náà láìmọ̀ nǹkan tó fẹ́ lọ ṣe ní London ní pàtó.

Ó tẹ̀síwájú pé tí wọ́n yọ kídìnrín ọmọ náà, ó ṣeéṣe kọ ṣe àkóbá fún-un ní ọjọ́ iwájú.

Wọ́n parọ́ pé ẹbí ni Sonia àti Ọmọ náà – Olùpejọ́

Davies tún ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ irọ́ ni wọ́n pa láti fẹ́ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹbí ni Sonia àti ọmọkùnrin náà.

Ó ní wọ́n ra ọ̀pọ̀ aṣọ fun láti bá Sonia ya àwòrán nítorí wọ́n fẹ́ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun àti Sonia ti ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ara wọn kó tó di àsìkò yìí.

Ó fi kun pé wọ́n gba gbogbo àkóso ayé ọmọkùnrin náà, tí wọ́n sì gba gbogbo ìwé ọwọ́ rẹ̀ títí ti wọ́n fi dé ibi tí wọ́n ti fẹ́ yọ kídìnrín rẹ̀.

Àwọn Ekweremadu mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àti dókìtà Obeta láti Southwark jiyàn pé àwọn kò mú ọkùnrin náà ]lọ sí London láti tẹ ẹ̀tọ́ rẹ̀ lójú.