Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Njẹ o mọ pe o ti le lọsẹ kan bayii ti ko ti si ina ni Ariwa Naijiria?
Ki lo de? Wọn gbayawo awọn oṣiṣẹ apinnaka ni?
O maa kọja bẹẹ, ọpọ nnkan lo ti bajẹ nitori aisi ina, Koda, awọn oniṣowo ti n sọ pe bii kawọn filu silẹ lo ri .
Ileeṣẹ to n pinna, TCN, sọ fun BBC pe ai si ina ko ṣẹyin awọn oju opo meji to bajẹ ni Shiroro ati Kaduna
Aṣe loootọ ni pe oju ni maaluu n rọ, ọbẹ o daa lọrun
Ko sẹni to fẹ ẹ ku
Bẹẹ gan-lori fun Ramon Adedoyin, to gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ nitori idajọ iku ti wọn da fun un lori iku Timothy Adegoke
Ẹkunrẹrẹ bi igbẹjọ naa ṣe waye wa ni bbc.com/yoruba
Ko sowo, ko siṣẹ
Se o ti gbagbe pe ẹni ti ko ba ṣiṣẹ, ko yẹ ko jẹun ni?
Awọn oṣiṣẹ fasiti lo ni awọn ko nii pada sẹnu iṣẹ titi ti ijọba yoo fi san owo to jẹ awọn
Ọjọ Aje ọsẹ yii ni wọn bẹrẹ iyanṣẹlodi, lori owo oṣu mẹrin tijọba jẹ wọn.
Lọ soju opo wa lati mọ bo ṣe n lọ














