Àwọn ọ̀dọ́ bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn l’Osun lórí ọ̀wọ́ngógó epo, iná mọ̀nàmọ́ná àti oúnjẹ

Oríṣun àwòrán, Tosin Adedokun
Ẹgbẹ awọn ọdọ kan ti wọn n pe ara wọn ni “Coalition Concern Youths” ti ṣe iwọde lori ọwọngogo oúnjẹ, iná mọnamọna ati epo bẹnitiro.
Iwọde naa lo waye niluu Osogbo nipinlẹ Osun.
Orin to gba ẹnu awọn ọdọ naa ni wi pe, “ebi n pa wa, ko sowo, ko si abo lori ẹmi ati dukia mọ ni Naijiria.”
Wọn tun n kọrin pe “Oluwa fa ijọba to niwa lara yaa, ki o wo ijọba naa lulẹ patapata.”

Oríṣun àwòrán, Tosin Adedokun
Owolabi Hassan,to jẹ aṣiwaju awọn ọdọ naa ti sọ pe awọn n fẹ ki ijọba Bola Tinubu da owo epo bẹnitiro ati owo ina mọnamọna pada si bo ṣe wa tẹlẹ ki ara le rọ araalu.
Wọn tun sọ pe awọn ko fẹ owo iranwọ ti ijọba apapọ fẹ ya awọn akẹkọọ.
Hassan tun tẹsiwaju pe, owo iranwọ fun ọmọ ile ẹkọ giga ko le tan isoro rara.
O ni awọn n fẹ ki ijọba Bola Ahmed Tinubu ro awọn ọdọ lagbara nipa pipese isẹ fun wọn.
Hassan tun salaye wi pe, iya to n jẹ awọn ọdọ ati araalu ni Naijiria ti peleke si lasiko ijọba Bola Ahmed Tinubu.
Ajafẹtọ ọmọniyan kan, Waheed Lawalda to wa nibi iwọde naa ni awọn ọdọ nikan kọ ni ọrọ yii kan, bẹẹ si ni ki se ọdọ nikan lo yẹ ko ṣe iwọde.
Waheed sọ pe “gbogbo wa lo yẹ ko se iwọde lori inira to doju kọ wa ni Naijiria, kii ṣe ọdọ nikan.
“Ọna abayọ ti awa ọmọ Naijiria ni ni ki gbogbo wa jade fun iwọde lori ọwọngogo epo bẹntiro, ina mọnamọna ati ọwọngogo ounjẹ.
Waheed Lawal wa rọ awọn agbofinro lati maa pese abo fun awọn oluwọde dipo ki wọn maa da wọn duro lasiko iwọde naa.















