Ẹnikẹ́ni tó bá ṣe owó náírà ní ìṣekúṣe lọ́wọ́ yìí yóò fojú winá òfin – Mínísítà ètò ìròyìn

Àkọlé fídíò, Ẹnikẹ́ni tí bá ṣe owó náírà ní ìṣekúṣe lọ́wọ́ yìí yóò fojú winá òfin – Mínísítà ètò ìròyìn
Ẹnikẹ́ni tó bá ṣe owó náírà ní ìṣekúṣe lọ́wọ́ yìí yóò fojú winá òfin – Mínísítà ètò ìròyìn
Aworan Minisita eto iroyin

Minisita eto iroyin, Mohammed Idris Malagi ti sọ pe ẹnikẹni to ba ṣe owo naira ni iṣekuṣe yoo foju wina ofin.

Ọgbẹni Malagi sọ fun BBC pe ‘’owo Naijiria kii ṣe ọna pasipaarọ fun wa nikan, O tun jẹ ọna idanimọ fun wa, ami ti pa wa pọ.

O jẹ iṣura orilẹede wa, nitori naa, ko si ẹni to maa ri bi wọn ṣe n tẹ iṣura mọlẹ ti inu rẹ maa dun.’’

Minisita eto iroyin fikun ọrọ rẹ pe ‘’ofin to de naira kii ṣe ofin tuntun, o ti wa ti tipẹ.

Koda, awọn eeyan kan ti foju ba ile ẹjọ tẹlẹ ri lori ẹsun ṣiṣe naira ni iṣekuṣe.

Ṣugbọn nitori wọn ki i ṣe awọn to lokiki ni ko jẹ ki ọpọ eeyan mọ nipa wọn.

Nnkan to jẹ tuntun ni pe awọn to jẹ gbajumọ gan an lawujọ naa ti n foju wina ofin ti wọn ba ti ṣe owo naira ni iṣekuṣe lọwọ yii.

Ofin yii wa nibẹ lati ṣe idiwọ fun titẹ naira mọlẹ tabi ṣiṣe owo naa ni iṣekuṣe.’’