Boris Johnson: Ìwádìí yóò bẹ̀rẹ̀ lórí ọrọ Niqob

Aworan Boris Johnson ati Obirin to wo ẹha

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọgbẹni Johnson faake kọri láti tọrọ aforijin lórí ọrọ tó sọ pé àwọn tó n wọ ẹha dàbí ole to daṣo bójú

O ṣeéṣe kí Boris Johnson káwó pọn yín rojọ lori pé o tápà sí òfin iwuwasi ẹgbẹ òṣèlú Conservative nílẹ Gẹẹsi.

Ẹgbẹ náà ni àwọn ti gba ọpọlọpọ ifehonuhan lórí ọrọ tí aṣojú ìjọba nílẹ okere tẹlẹ rí òun sọ nípa àwọn obìnrin tí wọn wọ Niqob.

Ìgbìmò kan ni yóò wo awọn ẹsun náà tí yóò si fí esi iwadi wọ́n ṣọwọ sí ìgbìmò aláṣẹ ẹgbẹ náà tó lágbára láti lè kúrò nínú ẹgbẹ.

Ẹgbẹ náà kọ láti se àlàyé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nipa iwadi òun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amin iyasọtọ kan
Awon awọn obinrin ti wọn wọ Niqob

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ẹlẹha n koju ipenija orisirisi lori imura wọn
Amin iyasọtọ kan

Agbẹnusọ ẹgbẹ Conservative kan ni òfin tó dé iwuwasi ẹgbẹ náà kí se nnkan ti àwọn le ma sọ nípa rẹ.

Èèyàn kan to sunmọ ọgbẹni Johnson kọ láti sọrọ.

Ọgbẹni Johnson faake kọri láti tọrọ aforijin lórí ọrọ tó sọ pé àwọn tó n wọ ẹha dàbí ole to daṣo bójú nínú afilekọ kan tó kọ nínú ìwé ìròyìn Telegraph.

Bákannáà ló ní kí wọn fòfin de wíwọ ẹha to bò ojú.

Awon awọn obinrin ti wọn wọ Niqob

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Awọn obinrin se iwọde lorileede Denmark lati fi ẹhonu han lori ofin to fi iya je obinrin to ba wọ iboju nita gbangba

Àwọn alatako ni o n rú iná sí ọrọ tó n takò ẹlẹsin musulumi kí o ba le gbégbá orókè nínú òṣèlú.

Ṣugbọn awọn alatilẹyin rẹ ni ọ n ja fún ẹtò awọn èèyàn ni.

Ẹnu kò sìn lára ẹgbẹ Conservative lori ẹsùn pé kò ṣápá láti dẹkùn ìwà àìtó sí àwọn mùsùlùmí t'óun ti igbese oríṣiríṣi to wa nile lati mú ibasepọ àlàfíà wa láàrin àwọn èèyàn ẹlẹyamẹya ẹlẹsin mẹsin.

Òfin ẹgbẹ náà ni àwọn tí wọn dipò mú gbọdọ jẹ ẹni awokọṣe tí kò ní lo ipò rẹ láti degun le awọn èèyàn tàbí fi iya jẹ wọn.

Ti won ba ri wí pé Johnson jẹbi,o ṣeeṣe kí wọn fi iya lile kúrò nínú ẹgbẹ je tabi ijiya mii ti ọ kéré.

Àkọlé fídíò, Falz: MURIC ní ọ̀rọ yí kọjá orin, wọ́n ni ó dilé ẹjọ́
Àkọlé fídíò, Wo imọran Fọlọrunṣọ Alakija fun awọn ọdọ adulawọ