Nibo l'akẹkọbirin Dapchi to ku l'ọwọ Boko Haram wa?

Patako ajuwe ile ẹkọ Dapchi, nipinlẹ Yobe

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ninu osu keji ni wọn ji awọn akẹkọbirin naa gbe lati ile iwe girama wọn to wa ni Dapchi, nipinlẹ Yobe.

Ọga ọlọpa Naijiria, Ibrahim Idris Kpotun ti ke gbajare pe oun ko sọ wipe lai pe ni wọn yoo tu akẹkọbirin Dapchi to ku l'ọwọ awọn Boko Haram Silẹ.

Eleyi wa ninu atẹjade kan lati ọdọ agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpa Naijiria, Jimọh Moshood.

Atẹjade naa sọ wipe wọn si ọga ọlọpa ọhun gbọ ni nitori pe ọrọ to sọ ko da lori akẹkọbirin Leah Sharibu to wa l'ọwọ Boko Haram.

Awọn iwe iroyin kan ti kọkọ sọ pe Ibrahim Idris ni lai pẹ ni wọn yoo tu akẹkọbirin Dapchi kan soso to ku l'ọwọ awọn Boko Haram silẹ.

Baalu ni wọn fi gbe awọn akẹkọbirin Dapchi ti Boko Haram tu silẹ lọ ri Aarẹ Buhari l'Abuja

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Baalu ni wọn fi gbe awọn akẹkọbirin Dapchi ti Boko Haram tu silẹ lọ ri Aarẹ Buhari l'Abuja

Ileese ọlọpa sọ wipe nnkan ti ọgọ ọlọpa naa sọ ni pe awọn akẹkọbirin ti wọn tu silẹ wọn yoo pada sile nipinlẹ Yobe.

Ọmọ mi ko ti de o!

Ọgbẹni Sharibu Nathan to jẹ baba fun Leah Sharibu to ku l'ọwọ awọn Boko Haram ninu awọn akẹkọbirin Dapchi lo sọ fun akọroyin BBC pe ọmọ oun ko ti de.

L'ọjọ Abamẹta ni awọn eeyan sa jade kuro ni abule Dapchi nigba ti wọn gbọ pe awọn Boko Haram n bọ wa si'lu wọn.

Nnkan ti awọn ara ilu naa gbọ ni pe o ṣeeṣe ki wọn o tu akẹkọbirin Leah Sharibusilẹ, iroyin sọ pe wọn ko tu silẹ nigba ti wọn tu awọn iyoku rẹ silẹ nitori pe o ni oun ko ni fi ẹsin Kristẹsni rẹ silẹ.

Sugbọn awọn ara-ilu pada wa sinu ilu Dapchi nigba ti wọn ko gburo Boko Haram tabi Leah Sharibu.