AFCON 2019: Orílẹ̀èdè wo ló tún leè mókè lẹ́ka míràn l‘Afirika

AFCON 2019
Idije ife ẹyẹ Afirika (AFCON) fọdun 2019 ti n lọ lọwọ, pẹlu orilẹede mẹrinlelogun to n figa gbaga lati jawe olubori. Amọ ta ba gbe oju kuro lori ohun to n lọ lori ọdan, a lee da ara wa laraya lati beere pe "Ta ni orilẹede ti yoo gbegba oroke ninu awọn nkan miran yatọ si ere bọọlu laarin awọn to n kopa ninu AFCON naa?" Ere ayo wa yii lo ko awọn orilẹede yii papọ lati doju kọ ara wọn, ka le mọ eyi ti intanẹti rẹ yara julọ, eyi ti ẹmi awọn eeyan rẹ n gun julọ, orilẹede ti iwa ajẹbanu ti kere julọ laarin wọn ati awọn ilana igbelewọn miran to se pataki.
Mu iṣọri igun kan
News image
  • Orilẹede wo lo ni intanẹti to yara ju?
    • Ìpele ikọ̀ mẹrindinlogun
        • Zimbabwe vs Kenya. Ẹni to bori: Kenya
        • South Africa vs Tunisia. Ẹni to bori: South Africa
        • Madagascar vs Côte d'Ivoire. Ẹni to bori: Madagascar
        • Ghana vs Mali. Ẹni to bori: Ghana
        • Angola vs Morocco. Ẹni to bori: Morocco
        • Senegal vs Congo DR. Ẹni to bori: Senegal
        • Nigeria vs Cameroon. Ẹni to bori: Nigeria
        • Uganda vs Tanzania. Ẹni to bori: Uganda
    • Ìpele to ṣaaju eyi to kangun si aṣekagba
        • Kenya vs South Africa. Ẹni to bori: South Africa
        • Madagascar vs Ghana. Ẹni to bori: Madagascar
        • Morocco vs Senegal. Ẹni to bori: Senegal
        • Nigeria vs Uganda. Ẹni to bori: Uganda
    • Ìpele to kangun si aṣakagba
        • South Africa vs Madagascar. Ẹni to bori: Madagascar
        • Senegal vs Uganda. Ẹni to bori: Senegal
    • Aṣekagba
        • Madagascar
          Senegal
          Madagascar vs Senegal. Ẹni to bori: Madagascar
    News imageNews image
    Madagascar
    Ni Osu Karun ọdun 2019, iyara kankan intanẹti Madagascar jẹ mẹgabaiti 28.08 ni iseju kan - eyi to jẹ intanẹti to yara sikeji nilẹ Afirika lẹyin Cape Verde. Amọ, bi intanẹti naa se yara to yii, eyi ko tumọ si pe wọn n lo intanẹti naa bo se yẹ. Gẹgẹ bii Banki Agbaye ti wi, 2017, idamẹwa awọn eniyan to wa ni orilẹede lo n lo intanẹti.
    Orisun: Speedtest Global Index latọwọ Ookla. Bi gbigba rẹ ṣe yara si lori ayelujara, oṣu karun, ọdun 2019. Ko si akọsilẹ fun Guinea-Bissau ati Guinea.
    News image
  • Orilẹede wo lo n jẹ irẹsi julọ?
    • Ìpele ikọ̀ mẹrindinlogun
        • Uganda vs Tanzania. Ẹni to bori: Tanzania
        • Côte d'Ivoire vs Ghana. Ẹni to bori: Côte d'Ivoire
        • Guinea vs Kenya. Ẹni to bori: Guinea
        • Guinea-Bissau vs Mauritania. Ẹni to bori: Guinea-Bissau
        • Mali vs South Africa. Ẹni to bori: Mali
        • Senegal vs Nigeria. Ẹni to bori: Senegal
        • Madagascar vs Benin. Ẹni to bori: Madagascar
        • Egypt vs Angola. Ẹni to bori: Egypt
    • Ìpele to ṣaaju eyi to kangun si aṣekagba
        • Tanzania vs Côte d'Ivoire. Ẹni to bori: Côte d'Ivoire
        • Guinea vs Guinea-Bissau. Ẹni to bori: Guinea
        • Mali vs Senegal. Ẹni to bori: Senegal
        • Madagascar vs Egypt. Ẹni to bori: Madagascar
    • Ìpele to kangun si aṣakagba
        • Côte d'Ivoire vs Guinea. Ẹni to bori: Guinea
        • Senegal vs Madagascar. Ẹni to bori: Senegal
    • Aṣekagba
        • Guinea
          Senegal
          Guinea vs Senegal. Ẹni to bori: Guinea
    News imageNews image
    Guinea
    Ni ọdun 2018, awọn eeyan orilẹede Guinea jẹ odiwọn aadọwa kilogiramu irẹsi. Bo tilẹ jẹ wi pe wọn ni oju ọjọ to dara fun ọgbin irẹsi, sibẹ irẹsi wa lara ounjẹ ti orilẹede naa n ko wọle julọ latilẹ okeere. Awọn orilẹede Asia ni wọn n ta irẹsi naa fun Guinea.
    Orisun: IRRI. Idiwọn bi wọn ti jẹ irẹsi si ni ọdun 2018. Ko si akọsilẹ fun Orilẹede Benin, Namibia, Tunisia ati Zimbabwe
    News image
  • Orilẹede wo ni ọrọ aje rẹ dara julọ?
    • Ìpele ikọ̀ mẹrindinlogun
        • Zimbabwe vs Kenya. Ẹni to bori: Kenya
        • South Africa vs Mauritania. Ẹni to bori: South Africa
        • Nigeria vs Morocco. Ẹni to bori: Morocco
        • Ghana vs Tunisia. Ẹni to bori: Tunisia
        • Angola vs Namibia. Ẹni to bori: Namibia
        • Algeria vs Benin. Ẹni to bori: Algeria
        • Guinea vs Cameroon. Ẹni to bori: Cameroon
        • Egypt vs Senegal. Ẹni to bori: Senegal
    • Ìpele to ṣaaju eyi to kangun si aṣekagba
        • Kenya vs South Africa. Ẹni to bori: South Africa
        • Morocco vs Tunisia. Ẹni to bori: Tunisia
        • Namibia vs Algeria. Ẹni to bori: Namibia
        • Cameroon vs Egypt. Ẹni to bori: Egypt
    • Ìpele to kangun si aṣakagba
        • South Africa vs Tunisia. Ẹni to bori: South Africa
        • Namibia vs Egypt. Ẹni to bori: Namibia
    • Aṣekagba
        • South Africa
          Namibia
          South Africa vs Namibia. Ẹni to bori: South Africa
    News imageNews image
    South Africa
    Ọrọ aje South Africa fi diẹ ju ti Amẹrika lọ pẹlu ẹgbẹrun mẹfa Dọla lọdun kan, gẹgẹ bi Banki agbaye ṣe sọ. Amọ orilẹede South Africa jẹ ọkan lara awọn orilẹede ti nkan o ti bara dọgba julọ lagbaye. Bi orilẹede naa tilẹ jẹ wi pe ibẹ ni awọn to lowo ju nilẹ Afirika pọju si, sibẹ, ni saa kẹrin ọdun 2018, ida mẹtadinlọgbọn ninu ọgọrun awọn eeyan orilẹede naa ni ko niṣẹ lọwọ. Isẹ ati osi si peleke si.
    Orisun: Banki Agbaye, (Ọrọ aje orilẹede), Dọla, ọdun 2017
    News image
  • Orilẹede wo ni ẹyawo rẹ nilẹ okeere kere julọ?
    • Ìpele ikọ̀ mẹrindinlogun
        • Egypt vs Tanzania. Ẹni to bori: Tanzania
        • Côte d'Ivoire vs Benin. Ẹni to bori: Benin
        • Nigeria vs Uganda. Ẹni to bori: Nigeria
        • Guinea-Bissau vs Angola. Ẹni to bori: Guinea-Bissau
        • Mali vs Morocco. Ẹni to bori: Mali
        • Algeria vs Burundi. Ẹni to bori: Algeria
        • Guinea vs Cameroon. Ẹni to bori: Guinea
        • Congo DR vs Kenya. Ẹni to bori: Congo DR
    • Ìpele to ṣaaju eyi to kangun si aṣekagba
        • Tanzania vs Benin. Ẹni to bori: Benin
        • Nigeria vs Guinea-Bissau. Ẹni to bori: Nigeria
        • Mali vs Algeria. Ẹni to bori: Algeria
        • Guinea vs Congo DR. Ẹni to bori: Congo DR
    • Ìpele to kangun si aṣakagba
        • Benin vs Nigeria. Ẹni to bori: Nigeria
        • Algeria vs Congo DR. Ẹni to bori: Algeria
    • Aṣekagba
        • Nigeria
          Algeria
          Nigeria vs Algeria. Ẹni to bori: Algeria
    News imageNews image
    Algeria
    Owo nla to n wọle lati ẹka ohun amuṣagbara ati owo nla ti wọn n fi pamọ sinu apo ẹdawo fun ifẹsẹmulẹ epo robi ti fun orilẹede Algeria lanfani lati fẹẹ san gbese ti wọn jẹ silẹ okere tan, eyi to jẹ idameta ati aabọ ninu gbogbo owo to n wọle fun orilẹede naa lọdun 2017. Eyi tumọ si wipe ni orilẹede Algeria, ti gbogbo ọmọ orilẹede naa ba pa owo oṣu ati ere to n wọle fun wọn papọ, yoo gba wọn ni ọjọ mejila gbako lati san gbese ti orilẹede naa jẹ si ilẹ okeere. Eyi yatọ si ohun to n ṣẹlẹ lorilẹede Mauritania, nibi ti yoo ti gba wọn to okooleọọdunrun o din mẹsan ọjọ.
    Orisun: Banki agbaye (IDS), Gbogbo gbese ti wọn jẹ soke okun. Amọ ko si akọsilẹ fun orilẹede Namibia
    News image
  • Orilẹede wo ni awọn eeyan ibẹ ti n pẹ laye julọ?
    • Ìpele ikọ̀ mẹrindinlogun
        • Uganda vs Senegal. Ẹni to bori: Senegal
        • Morocco vs Angola. Ẹni to bori: Morocco
        • Nigeria vs South Africa. Ẹni to bori: South Africa
        • Ghana vs Mauritania. Ẹni to bori: Mauritania
        • Tunisia vs Namibia. Ẹni to bori: Tunisia
        • Algeria vs Cameroon. Ẹni to bori: Algeria
        • Madagascar vs Benin. Ẹni to bori: Benin
        • Egypt vs Tanzania. Ẹni to bori: Egypt
    • Ìpele to ṣaaju eyi to kangun si aṣekagba
        • Senegal vs Morocco. Ẹni to bori: Morocco
        • South Africa vs Mauritania. Ẹni to bori: Mauritania
        • Tunisia vs Algeria. Ẹni to bori: Tunisia
        • Benin vs Egypt. Ẹni to bori: Egypt
    • Ìpele to kangun si aṣakagba
        • Morocco vs Mauritania. Ẹni to bori: Morocco
        • Tunisia vs Egypt. Ẹni to bori: Tunisia
    • Aṣekagba
        • Morocco
          Tunisia
          Morocco vs Tunisia. Ẹni to bori: Tunisia
    News imageNews image
    Tunisia
    Awọn ọmọ orilẹede Tunisia ti wọn bi lọdun 2017 ni ireti wa pe wọn yoo lo ọdun mejidinlọgọrin laye - mẹtadinlaadọrin ninu wọn yoo ni ilera to peye. Awọn obinrin nireti wa pe wọn yoo lo ọgọrin ọdun laye, tawọn ọkunrin yoo si lo ọdun mẹrindinlọgọrin. Orisun iku aitọjọ lorilẹede naa ni aisan ọkan ati ijamba mọto.
    Iwadi ajọ Global Burden disease lọdun 2017, pẹlu ibudo Health Metrics and Evaluation. Ṣe akojọpọ ọmọ tuntun ti yoo ye nigba ti wọn ba bi, takọ-tabo.
    News image
  • Orilẹede wo lo ni eeyan to pọ julọ?
    • Ìpele ikọ̀ mẹrindinlogun
        • Congo DR vs Kenya. Ẹni to bori: Congo DR
        • South Africa vs Guinea. Ẹni to bori: South Africa
        • Nigeria vs Côte d'Ivoire. Ẹni to bori: Nigeria
        • Ghana vs Mali. Ẹni to bori: Ghana
        • Angola vs Morocco. Ẹni to bori: Morocco
        • Tanzania vs Uganda. Ẹni to bori: Tanzania
        • Madagascar vs Cameroon. Ẹni to bori: Madagascar
        • Egypt vs Algeria. Ẹni to bori: Egypt
    • Ìpele to ṣaaju eyi to kangun si aṣekagba
        • Congo DR vs South Africa. Ẹni to bori: Congo DR
        • Nigeria vs Ghana. Ẹni to bori: Nigeria
        • Morocco vs Tanzania. Ẹni to bori: Tanzania
        • Madagascar vs Egypt. Ẹni to bori: Egypt
    • Ìpele to kangun si aṣakagba
        • Congo DR vs Nigeria. Ẹni to bori: Nigeria
        • Tanzania vs Egypt. Ẹni to bori: Egypt
    • Aṣekagba
        • Nigeria
          Egypt
          Nigeria vs Egypt. Ẹni to bori: Nigeria
    News imageNews image
    Nigeria
    Orilẹede Naijiria ni orilẹede ti eeyan inu rẹ pọ julọ nilẹ Afirika, pẹlu eeyan to le ni igba miliọnu, to si wa ni ipo keje lagbaye. Awọn eeyan orilẹede Naijiria jẹ ọdọ: mẹrin ninu mẹwa awọn eeyan Naijiria ni ọjọ ori wọn ko to ọdun mẹrinla.
    Orisun: Iwe akọsilẹ ajọ to n sewadi iwa ọdaran, CIA World Factbook, akojọp iye eeyan ldun 2018
    News image
  • Orilẹede wo lo ni ilẹ to pọ julọ?
    • Ìpele ikọ̀ mẹrindinlogun
        • Egypt vs Tanzania. Ẹni to bori: Egypt
        • South Africa vs Mauritania. Ẹni to bori: South Africa
        • Nigeria vs Morocco. Ẹni to bori: Nigeria
        • Cameroon vs Mali. Ẹni to bori: Mali
        • Angola vs Namibia. Ẹni to bori: Angola
        • Algeria vs Zimbabwe. Ẹni to bori: Algeria
        • Madagascar vs Ghana. Ẹni to bori: Madagascar
        • Congo DR vs Kenya. Ẹni to bori: Congo DR
    • Ìpele to ṣaaju eyi to kangun si aṣekagba
        • Egypt vs South Africa. Ẹni to bori: South Africa
        • Nigeria vs Mali. Ẹni to bori: Nigeria
        • Angola vs Algeria. Ẹni to bori: Algeria
        • Madagascar vs Congo DR. Ẹni to bori: Congo DR
    • Ìpele to kangun si aṣakagba
        • South Africa vs Mali. Ẹni to bori: Mali
        • Algeria vs Congo DR. Ẹni to bori: Algeria
    • Aṣekagba
        • Mali
          Algeria
          Mali vs Algeria. Ẹni to bori: Algeria
    News imageNews image
    Algeria
    Orilẹede Algeria lo ni ilẹ to fẹ julọ ni Afirika, to si wa ni ipo karun lagbaye. O le ni ida ọgọrin ninu ilẹ to wa orilẹede Algeria to jẹ asalẹ Sahara. Tẹlẹtẹlẹ, orilẹede Sudan lo ni ilẹ to fẹ julọ ni Afirika, ko to di pe wọn pin lọdun 2011. Awọn eeyan ko pọ pupọ lorilẹede Algeria, eeyan mẹtadinlogun si lo ni kilomita kan, eyi ti ko ri bẹẹ ni orilẹede Burundi, ti eeyan okoolenirinwo ati mẹta n lo kilomita kan.
    Orisun: Banki agbaye, 2018
    News image
  • Orilẹede wo ni wọn woye pe isẹlẹ iwa ajẹbanu ko ti wọpọ?
    • Ìpele ikọ̀ mẹrindinlogun
        • Uganda vs Tanzania. Ẹni to bori: Tanzania
        • Namibia vs Mauritania. Ẹni to bori: Namibia
        • Guinea vs Morocco. Ẹni to bori: Morocco
        • Ghana vs Mali. Ẹni to bori: Ghana
        • Tunisia vs South Africa. Ẹni to bori: South Africa
        • Senegal vs Cameroon. Ẹni to bori: Senegal
        • Nigeria vs Benin. Ẹni to bori: Benin
        • Egypt vs Algeria. Ẹni to bori: Algeria
    • Ìpele to ṣaaju eyi to kangun si aṣekagba
        • Tanzania vs Namibia. Ẹni to bori: Namibia
        • Morocco vs Ghana. Ẹni to bori: Morocco
        • South Africa vs Senegal. Ẹni to bori: Senegal
        • Benin vs Algeria. Ẹni to bori: Benin
    • Ìpele to kangun si aṣakagba
        • Namibia vs Morocco. Ẹni to bori: Namibia
        • Senegal vs Benin. Ẹni to bori: Senegal
    • Aṣekagba
        • Namibia
          Senegal
          Namibia vs Senegal. Ẹni to bori: Namibia
    News imageNews image
    Namibia
    Orilẹede Namibia ni wọn lero pe iwa ajẹbanu ti kere julọ lẹka isẹ ọba laarin awọn orilẹede to n dije fun ife ẹyẹ il Afirika, AFCON, to si n lewaju orilẹede Senegal. Gẹgẹ bi akọsilẹ iwadi iwa ajẹbanu lọdun 2018 se safihan rẹ, Nambia lo se ipo karun nilẹ Afirika, orilẹede Seychelles si lo n lewaju. Lagbaye, orilẹede yii tun siwaju Italy ati Turkey.
    Orisun: Akọsilẹ iwa ajẹbanu fọdun 2018 ti ajọ Transparency International se
    News image
  • Orilede wo ni inu awọn eeyan rẹ dun julọ?
    • Ìpele ikọ̀ mẹrindinlogun
        • Uganda vs Senegal. Ẹni to bori: Senegal
        • Morocco vs Mali. Ẹni to bori: Morocco
        • Nigeria vs South Africa. Ẹni to bori: Nigeria
        • Cameroon vs Tunisia. Ẹni to bori: Cameroon
        • Mauritania vs Côte d'Ivoire. Ẹni to bori: Côte d'Ivoire
        • Algeria vs Benin. Ẹni to bori: Algeria
        • Guinea vs Ghana. Ẹni to bori: Ghana
        • Congo DR vs Kenya. Ẹni to bori: Kenya
    • Ìpele to ṣaaju eyi to kangun si aṣekagba
        • Senegal vs Morocco. Ẹni to bori: Morocco
        • Nigeria vs Cameroon. Ẹni to bori: Nigeria
        • Côte d'Ivoire vs Algeria. Ẹni to bori: Algeria
        • Ghana vs Kenya. Ẹni to bori: Ghana
    • Ìpele to kangun si aṣakagba
        • Morocco vs Nigeria. Ẹni to bori: Nigeria
        • Algeria vs Ghana. Ẹni to bori: Algeria
    • Aṣekagba
        • Nigeria
          Algeria
          Nigeria vs Algeria. Ẹni to bori: Nigeria
    News imageNews image
    Nigeria
    Orilẹede Naijiria lo n lewaju ninu awọn orilẹede to n dije fun ife ẹyẹ́ ilẹ Afirika, AFCON, ti inu wọn dun julọ̀, gẹgẹ bi abọ iwadi idunnu lagbaye tọdun 2019 ti wi, eyi to se agbeyẹwo awọn nkan wọnyii: owo to n wọle, awọn eeyan ti ara wọn ji pepe, atilẹyin lati ọdọ awujọ, ominira, aisi iwa ajẹbanu ati ififunni. Lagbaye, orilẹede Naijiria lo wa ni ipo karunlelọgọrin, to si gbewọn si ju ipo kọkanlelaadọrun to mu lọdun to kọja lọ. Naijiria yii si lo se ipo keji nilẹ Afirika, to si n tẹle orilẹede Mauritius lẹyin.
    Source: Abọ iwadi idunnu lagbaye tọdun 2019. Orilẹede Angola ati Guinea-Bissau ko si lara eto yii.
    News image
  • Orilẹede wo lo ni awọn obinrin to pọ julọ nile asofin rẹ?
    • Ìpele ikọ̀ mẹrindinlogun
        • Zimbabwe vs Tanzania. Ẹni to bori: Tanzania
        • Namibia vs Mauritania. Ẹni to bori: Namibia
        • Burundi vs Morocco. Ẹni to bori: Burundi
        • Angola vs Cameroon. Ẹni to bori: Angola
        • Tunisia vs South Africa. Ẹni to bori: South Africa
        • Senegal vs Madagascar. Ẹni to bori: Senegal
        • Guinea vs Guinea-Bissau. Ẹni to bori: Guinea
        • Uganda vs Algeria. Ẹni to bori: Uganda
    • Ìpele to ṣaaju eyi to kangun si aṣekagba
        • Tanzania vs Namibia. Ẹni to bori: Namibia
        • Burundi vs Cameroon. Ẹni to bori: Burundi
        • South Africa vs Senegal. Ẹni to bori: South Africa
        • Guinea vs Uganda. Ẹni to bori: Uganda
    • Ìpele to kangun si aṣakagba
        • Namibia vs Burundi. Ẹni to bori: Namibia
        • South Africa vs Uganda. Ẹni to bori: South Africa
    • Aṣekagba
        • Namibia
          South Africa
          Namibia vs South Africa. Ẹni to bori: Namibia
    News imageNews image
    Namibia
    Ni orilẹede Namibia, ida mẹrindinlaadọta ninu ọgọrun ni awọn obinrin ko nile aṣofin kekere rẹ. Eyi tumọ si pe orilẹede yii lo se ipo keji nilẹ Afirika lẹyin orilẹede to se ipo kinni lagbaye, Rwanda. Namibia yii naa lo wa ni ipo kẹwa lagbaye ninu abọ iwadi nipa alafo to n bẹ laarin akọ ati abo lọdun 2018, to si n lewaju orilẹede Germany ati ilu Ọ́ba, UK.
    Orisun: Ẹgbẹ ẹka asofin kan si ekeji, ida obinrin to wa nile titi di ọjọ kinni, oṣu keji ọdun 2019.
    News image
  • Orilẹede wo lo gba ami ẹyẹ wura to pọ julọ ninu idije ere idaraya Olympics?
    • Ìpele ikọ̀ mẹrindinlogun
        • Zimbabwe vs Algeria. Ẹni to bori: Algeria
        • South Africa vs Madagascar. Ẹni to bori: South Africa
        • Nigeria vs Côte d'Ivoire. Ẹni to bori: Nigeria
        • Cameroon vs Angola. Ẹni to bori: Cameroon
        • Tunisia vs Morocco. Ẹni to bori: Morocco
        • Kenya vs Uganda. Ẹni to bori: Kenya
        • Burundi vs Ghana. Ẹni to bori: Burundi
        • Egypt vs Tanzania. Ẹni to bori: Egypt
    • Ìpele to ṣaaju eyi to kangun si aṣekagba
        • Algeria vs South Africa. Ẹni to bori: South Africa
        • Nigeria vs Cameroon. Ẹni to bori: Nigeria
        • Morocco vs Kenya. Ẹni to bori: Kenya
        • Burundi vs Egypt. Ẹni to bori: Egypt
    • Ìpele to kangun si aṣakagba
        • South Africa vs Nigeria. Ẹni to bori: South Africa
        • Kenya vs Egypt. Ẹni to bori: Kenya
    • Aṣekagba
        • South Africa
          Kenya
          South Africa vs Kenya. Ẹni to bori: Kenya
    News imageNews image
    Kenya
    Orilẹede Kenya lo se ipo kinni ninu idije ere idaraya Olympics, pẹlu wura mọkanlelọgbọn, fadaka mejidinlogoji ati baba mẹrinlelọgbọn. orilẹede Kenya yii lo gba ami ẹyẹ ninu gbogbo ere idaraya to ti kopa, to si se aseyọri nla ninu ere sisa onibusọ gbọọrọ.Eliud Kipchoge to gba ami ẹyẹ wura nibi idije ere idaraya Olympics to waye nilu Rio, naa lo jẹ ẹni to le e sare onibusọ gbọọrọ julọ̀ lagbaye, to si n lo wakati meji, isẹju kan ati winni-winni mọkandinlogoji.
    Orisun: Ajọ to n se kokari ere idaraya Olympics, IOC titi di ọdun 2016.
    News image
  • Orilẹede wo lo ni ibudo ajogunba ti Unesco julọ lagbaye?
    • Ìpele ikọ̀ mẹrindinlogun
        • Congo DR vs Senegal. Ẹni to bori: Senegal
        • South Africa vs Benin. Ẹni to bori: South Africa
        • Madagascar vs Côte d'Ivoire. Ẹni to bori: Côte d'Ivoire
        • Cameroon vs Mali. Ẹni to bori: Mali
        • Tunisia vs Morocco. Ẹni to bori: Morocco
        • Kenya vs Zimbabwe. Ẹni to bori: Kenya
        • Nigeria vs Ghana. Ẹni to bori: Nigeria
        • Egypt vs Algeria. Ẹni to bori: Egypt
    • Ìpele to ṣaaju eyi to kangun si aṣekagba
        • Senegal vs South Africa. Ẹni to bori: South Africa
        • Côte d'Ivoire vs Mali. Ẹni to bori: Mali
        • Morocco vs Kenya. Ẹni to bori: Morocco
        • Nigeria vs Egypt. Ẹni to bori: Egypt
    • Ìpele to kangun si aṣakagba
        • South Africa vs Mali. Ẹni to bori: South Africa
        • Morocco vs Egypt. Ẹni to bori: Morocco
    • Aṣekagba
        • South Africa
          Morocco
          South Africa vs Morocco. Ẹni to bori: South Africa
    News imageNews image
    South Africa
    Orilẹede South Afrika ni orilẹede ilẹ Afirika to ni ibudo ajogunba ti Unesco julọ lagbaye, ti apapọ wọn jẹ mẹwa. Akọkọ ibudo ajogunba yii ti wọn gbe kalẹ lọdun 1999 ni ibudo Fossil Hominid ti South Afrika - pẹlu sise awari ibudo ti agbari Taung wa - to fi mọ ibudo igbafẹ Wetland ati erekusu Robben
    Orisun: Ajọ Unesco. O n ka awọn ibudo agbaye to wa ni orilẹede kọọkan
    News image
    • Algeria
    • Angola
    • Benin
    • Burundi
    • Cameroon
    • Congo DR
    • Côte d'Ivoire
    • Egypt
    • Ghana
    • Guinea
    • Guinea-Bissau
    • Kenya
    • Madagascar
    • Mali
    • Mauritania
    • Morocco
    • Namibia
    • Nigeria
    • Senegal
    • South Africa
    • Tanzania
    • Tunisia
    • Uganda
    • Zimbabwe
Orisun
Olawale Malomo ati Elisabetta Tollardo lo jẹ olootu isẹ yii, Olawale Malomo lo mu agbega baa, Millicent Wachira lo se agbekalẹ rẹ, Aaron Akinyẹmi, Anthony Makokha ati Muthoni Muchiri si lo se afikun isẹ iwadi nipa rẹ.
Ilana ti wọn lo lati se isẹ yii
Awọn orilẹede to n kopa ninu idije ife ẹyẹ ilẹ Afirika, AFCON, ni wọn se igbelewọn wọn nibamu pẹlu bi wọn ti pegede si ni ilana odiwọn mejila, ti wọn si ri orilẹede to pegede julọ laarin wọn bii orilẹede to gbegba oroke. Ikọọkan awọn orilẹede yii ni wọn fẹsẹ wọnsẹ pẹlu ara wọn nibamu pẹlu agbekalẹ tabili idije ti awọn osisẹ to n se kokari idije AFCON gbe kalẹ ati ofin to de abala Komẹsẹ o yọ̀. Nibiti orilẹede meji ba ti wa nipo kannaa ninu igbelewọn kan, igbelewọn awọn dun to ti kọja ni wọn yoo lo lati yanju rẹ. Awọn ami ẹyẹ Olympics ati awọn ibudo ajogunba agbaye ti Unesco nikan ni ofin yii ko kan. Fun awọn ami ẹyẹ Olympics, wọn to awọn orilẹede nibamu pẹlu iye wura, fadaka ati baba ti wọn gba - wọ̀n si pin okun to de wọn niya gẹgẹ bo se tọ. Nibiti orilẹede kan ko ba ti gba ami ẹyẹ kankan, wọn yoo se igbelewọn rẹ nibamu pẹlu iye awọn elere idaraya to ko wa sibi idije ere idaraya Olympics lọdun to kọja. Ni ti awọn ibudo ajogunba Unesco ẹwẹ, wọn maa n ge okun to de wọn nipa sise agbeyẹwo iye ibudo ajogunba to wa ninu akọsilẹ ajọ Unesco, eyi to n yẹ wo lọwọ-lọwọ.