Àwọn ǹkan tí yóò t'ẹyin kíkógbá iléeṣẹ́ tó n sójú Nàìjíríà nílẹ̀ láwọn orílè-èdè márùn

Aworan Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Owo ni b'oun o ba si nile ki wọn ma da imọran kankan lẹyin ohun.

Ẹyin odi ni owo ko ti si ti eleyi si mu ki ijọba orileede Naijiria kede pe ohun yoo kogba awọn ọfisi kan to n soju rẹ nilẹ okere wọle.

Sri Lanka, Czech Republic ati Serbia ni Minisita fọrọ ilẹ okere kede pe awọn yoo ti pa.

Àkọlé fídíò, Àìríṣẹ́ṣe ló mú àwọn ọ̀dọ̀ fẹ̀mí wọn wéwu
Àkọlé fídíò, Ẹtàn ni àwọn ọ̀rẹ́ fi ń tan èèyàn lọ si Libya pé iṣẹ́ gidi wà níbẹ̀

O fi kun un pe awọn yoo mu adinku ba iye eeyan to n ṣiṣẹ ni ile iṣẹ Naijiria to wa ni orileede Ukraine tori pe ko si owo.

Lapapọ wọn ti ile iṣẹ orileede Naijiria mẹta pa.

Ilesanmi dun ju oye lọ

Onwoye kan lori ọrọ aje ati oṣelu to fi ilu Eko ṣe ibujoko, Sam Olisha sọ fun BBC pe o ṣeni laaanu pe iru nkan bayi n ṣẹlẹ.

O ni nibi ti awọn orileede miiran ti n ṣi ileeṣẹ aṣoju kaakiri, o jẹ ohun ibanujẹ pe Naijiria n ti awọn tiẹ pa.

O ni ko jọ ohun loju nitori pe tẹlẹ naa ko si ipa ti awọn ileeṣẹ aṣoju orileede Naijiria n ṣe fawọn to wa nilẹ okere.

Àkọlé fídíò, 'A fẹ́ kí àwọn sẹ́nétọ̀ gba ẹlòmíì láàyè'

''Nibi ti a ti ni awọn ileeṣẹ wọnyii, ki ni ipa ti wọn ni? Lọpọ igba ti o ba ti kuro ni Naijiria, o ku ọ ku iwa rẹ lẹyin odi''

Ọgbẹni ni ara kudiẹ́kudiẹ to wa lara ijọba nile lo lọ farahan han lẹyin odi.

Amọ ṣa o ni kaka ki wọn ni ileeṣẹ ti ko ni ṣanfani fọmọ Naijiria, o san ki wọn kuku ti wọn pa.

Kini yoo tẹyin igbesẹ yi bọ?

Ṣaṣa ni orileede agbaye ti eeyan yoo de ti ko ti ni ba ọmọ Naijiria.

Yala wọn lọ kawe ni tabi lati lọ ṣowo, ileeṣẹ orileede wọn ni ilẹ ti wọn lọ a ma ṣe awọn iṣẹ kan ti yoo mu igbayegbadun rọrun fun wọn nibẹ.

Diẹ lara awọn nnkan ti igbesẹ yi yoo mu ba awọn ọmọ Naijiria nibẹ ni:

  • Gbigba pali idanimọ orileede Naijiria eleyi ti o ba ti jọba le fẹ soro diẹ. Idi ni pe ẹni naa yoo ni lati lọ si orileede mii to ba wa ni tosi to ni ileeṣẹ Naijiria lati lo gba pali tuntun mi ni.
  • Yatọ si pali ti yoo lọ gba, o gbọdọ ni iwe aṣẹ lati le wọ inu ilẹ bẹẹ eleyi ti oloyinbo n pe ni Visa. Wahala gbigba Visa a maa mu inira ba ọpọ lẹyin odi.
  • Fawọn to ba jẹ akẹkọ,awọn ohun ti wọn ma n ṣe ni irọrun tẹlẹ nipa iforukọsilẹ yoo mu wahala lọwọ nitori aisi ileeṣẹ orileede Naijiria nibẹ mọ
  • Awọn olokoowo ati ọlọrọ aje miiran naa yoo koju iṣoro pẹlu awọn iwe idanimọ kan ti o ba yẹ ki wọn gba nirọrun lati ọdọ awọn oṣiṣẹ ọfisi orileede wọn nibẹ.
  • Bibọwọ fun awọn ọmọ Naijiria le mẹhẹ diẹ nigba ti ko ba ti si ẹni ti wọn yoo sa lọ ba gẹgẹ bi aṣoju ilẹ wọn lẹyin odi.

Lai pẹ yii ni Minisita fọrọ ilẹ okere ni ijọba yoo ti awọn ile iṣẹ aṣoju Naijiria kan pa nitori aisi owo to to.