Minimum wage: Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti ìjọba àpapọ̀ fẹnukò lórí àbá òfin ẹ̀kúnwó oṣù

Awọn oṣiṣẹ n wọde
Àkọlé àwòrán, Ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kíní ni ìjọba yóò gbé àbá òfin náà lọ síwájú ilé aṣòfin àpapọ̀.

Ẹgbẹ oṣiẹ ati ijọba apapọ ti fẹnuko lori adehun bi aba ofin ẹkunwo oṣu tuntun yoo ṣe de ọwọ awọn aṣofin apapọ.

Ọjọ iṣẹgun, ti awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ gunle iyanṣẹlodi jakejado orilẹede Naijiria ni ifẹnuko naa to kẹsẹjari lẹyin ifikunlukun ọjọ mẹta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bii minisita fọrọ oṣiṣẹ ati igbanisiṣẹ, Dokita Chris Ngige ni ijọba apapọ yoo gbe aba ofin ẹkunwo osu tuntun naa ṣọwọ sọdọ awọn aṣofin apapọ ni ọjọ kẹtalelogun oṣu kini ọdun 2019 bi awọn aṣofin naa ba wọle pada sẹnu iṣẹ.

Àkọlé fídíò, Orangun: Èdè àti àṣà Yorùba ní láti jọ wá lójú

O ni gbogbo awọn ipade igbimọ iṣakoso gbogbo to yẹ ni aba naa yoo de ki wọn to gbee lọ siwaju awọn aṣofin apapọ.

Amọṣa, awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣiṣẹ ti kilọ fun ijọba apapọ pe ko gbọdọ fi ọbẹ ẹyin jẹ awọn oṣiṣẹ niṣu lori adehun naa.