Eto ilana ẹkọ ti ọdun 1999 ni ki ijọba pese eto ẹkọ ọfẹ fun awọn akẹẹkọ ni ile iwe alakọbẹrẹ. Awọn akẹẹkọ gbọdọ lọ si ile iwe alakọbẹrẹ ati ọdun mẹta to saaju ni girama, amọ ti ijọba ipinlẹ ko nii san owo yii.
Ilana yii ko sọ iye akọ ati abo ti wọn gbọdọ lo si ile iwe ni igba kan naa, ṣugbọn lorilẹede Naijiria bayii, awọn ọkunrin n lọ si ile iwe ju awọn obinrin lọ.
Nitorina ipese ma n wa fun awọn obinrin lati le wọ ile iwe ki iye wọn ba le dọgba pẹlu awọn ọkunrin wọn.
Ẹka Ajọ Isọkan Agbaye to n risi eto ẹkọ, Unesco sọ wi pe eto igbani si ile iwe laarin akọ si abọ, gbọdọ jẹ 98 ati 102 awọn obinrin si iye 100 ọkunrin to ba wọle si ile iwe.
Amọ, ayẹwo fihan wi pe o din ni ipinlẹ kan ninu mẹta to n wo iye awọn obinrin si ọkunrin to wa ni ile iwe alakọbẹrẹ. Ni ile iwe girama ti ọlọdun mẹta ti ipele akọkọ, ipinlẹ mẹsan lo ni eto yii, nigbati ile iwe girama ti awọn akẹẹkọjade ko ju ipinlẹ mẹta.
Ipinlẹ Ekiti lo ṣe daadaa ju nipa wiwo alafo to wa laarin akọ sabo ni gbogbo ipele eto ẹkọ.
Katsina lo gbẹyin ninu eto yii, 170,000 ni iye ọkunrin fi ma n po ju obinrin lọ ni ile iwe alakọbẹrẹ. Nigbati ile iwe girama ọlọdun mẹta akọkọ ma n fi 43,000 po ju awọn obinrin lọ. Nigbati 44,500 ọkunrin po ju obinrin lọ ni ile iwe girama ọlọdun mẹta alakọjade.
Ṣugbọn ipinlẹ Zamfara lo buruju nipa gbi gba awọn ọmọbinrin si ile-iwe. Ni gbogbo eto ile iwe ni iye awọn ọkunrin ti pọ ju awọn obinrin lọ ni ilọpo meji.
Iru eto ẹkọ ti awọn ọmọ yii n gba ni ile iwe naa ṣe pataki. Gẹgẹ bi akọsilẹ Ajọ Nigerian Education Data Survey (NEDS) ni ọdun 2015, 44% awọn akẹẹkọ to wa ni ile-iwe alakọbẹrẹ ti ijọba lo mọ iwee ka, nigbati 74% awọn akẹẹkọ to wa ni ile iwe aladani lo mọ iwe ka. Amọ, ni ile iwe ti ọlọdun mẹta akọkọ ni girama, awọn to mọ iwee ka ati kikọ jẹ 91% ati 96%.
Aarẹ Buhari ti seleri lati fi 15% owo isuna ọdun si eto ẹko, amọ akọsilẹ isejọba rẹ fihan wi pe o nilo lati se ju bẹẹ lọ lati le mu ileri naa ṣẹ.
Ni ọdun 2016, ijọba Buhari fi 8% owo isuna si eto ẹkọ ati ni ọdun 2017 ni o walẹ si 7.4%. Ni ọdun 2018, 7% ni wọn ya sọtọ lara owo isuna ọdun to jẹ bii 650bn naira ($1.8bn, £1.4bn).
Bi Aarẹ Buhari ba fẹ mu ileri rẹ sẹ, o gbọdọ fi kun owo isuna eto ẹkọ si bii 1.3tn naira, tabi ki o din owo isuna ẹka miiran ku.