Osinbajo: Buhari kò gbàgbé àwọn agbègbè tí ikọlù tú ká

Yẹmi Osibajo

Oríṣun àwòrán, @ProfOsinbajo

Àkọlé àwòrán, Gomina Ortom ni abẹwo Osibajo yoo fun awọn eeyan ipinlẹ Benue ni ireti

Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu biliọnu mẹwa naira fun atunṣe awọn ileto ti ikọlu awọn agbebọn bajẹ kaakiri tibu-toro orilẹede Naijiria.

Igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọsibajọ lo sọ eyi lasiko to fi ṣe abẹwo sawọn ibudo ogunlende kan nipinlẹ Benue ni irọlẹ ọjọ iṣẹgun.

Igbakeji aarẹ Oṣibajọ ṣalaye fun awọn olugbe ibudo ogunlende ni Abagena nibi ti awọn eeyan to le ni ẹgbẹ mẹrinlelọgbọn wa, pe ijọba apapọ n sa ipa lati ṣe atunto awọn agbegbe ti ikọlu ti waye lọna ati rii pe aabo ati irọrun pada sibẹ ki awọn olugbe ibẹ lee pada si ilẹ abinibi wọn laifoya.

Osibajo gúnlẹ̀ sí ibùdó ogunléndé ni Benue

Oríṣun àwòrán, @akandeoj

Àkọlé àwòrán, Osibajo gúnlẹ̀ sí Benue láti ṣe àyẹ̀wò si àwọn ibùdó ogunléndé

Ninu ọrọ rẹ, gomina Ortom ti ipinlẹ Benue dupẹ lọwọ aarẹ Buhari ati igbakeji rẹ fun aigbagbe awọn eeyan ipinlẹ naa ati ipenija wọn.

Gomina Ortom ni abẹwo igbakeji aarẹ Osibajo yoo tubọ fun awọn eeyan ipinlẹ Benue, paapaajulọ awọn ti rogbodiyan le kuro ni ileto wọn ni ireti irapada.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni asiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, igbakeji aarẹ ati awọn alẹnulọrọ nipinlẹ Benue n ṣe ipade apero lọwọ nibi ti wọn ti n sọ ẹdun ọkan wọn fun un ti oun pẹlu si n tẹti lori ọna ati gba da alaafia to tọjọ pada si ipinlẹ na.