Bùhárí buwọ́lù ìdásílẹ̀ iléeṣẹ́ ọmọogun tuntun ní Birnin Gwari

Oríṣun àwòrán, NIGERIA PRESIDENCY
Ààrẹ Mùhámádù Bùhárí ti buwọ́lù ìdásílẹ̀ ọ̀wọ́ iléeṣẹ́ ọmọogun tuntun àti àwọn iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tuntun lágbègbè Birnin Gwari ní ìpínlẹ̀ Kaduna.
Ààrẹ Bùhárí gbé ìgbésẹ̀ náà lẹ́yìn ìkọlù àti ìpànìyàn tó wáyé níbẹ̀.
Lọ́jọ́ àbámẹ́ta làwọn agbébọn kan kọlu agbègbè Birnin Gwari níbi tí wọ́n ti dáná sun àwọn ilé tí wọ́n sì tún pa àwọn èèyàn tí ọlọ́pàá ní kò dín ní márùn dín láàdọ́ta.
Ilẹ́eṣẹ́ ààrẹ ní ìkọlù náà dun ààrẹ Mùhámádù Bùhárí dé ọ́kàn tí ó sì ti ń gbé ìgbésẹ láti yànàná ìpèníjà àbò lágbègbè náà àti orílẹ̀èdè Nàíjíríà lápapọ̀.








