Dogara: Ohunkóhun kò gbọdọ̀ ṣe Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, @HouseNGR
Olórí ilé aṣojú-ṣòfin lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Yakubu Dogara, ti f'ohùn ránṣẹ́ s'awọn agbófínró pé ohunkóhun kò gbọdọ̀ ṣe Sẹ́nétọ̀ Dino Melaye ti wọ́n gbé lọ sílé ẹjọ́ lórí kẹ̀kẹ́ aláìsàn lọ́jọ́ ọ̀rú àti ọjọ́bọ.
Níbi ìjòkó ilé ni Dogara ti sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí aṣòfin Sunday Karimi, láti ìpínlè Kogi pe àkíyèsí ilé náà sí ìgbésẹ̀ àwọn ọlọ́pàá láti gbé Melaye lọ sí ilé ẹjọ́ lórí kẹ̀kẹ̀ aláìsàn.Dogara ní "a kò leè torí pé a fẹ́ gbé èèyàn kan lọ síwájú ilé ẹjọ́, ká gba ẹ̀mí lẹ́nu ẹni bẹ́ẹ̀. Bì ohunkóhun bá ṣe Dino, àwọn agbófínró ni yóò forí fá a."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Mi kò rí orílè-èdè tí wọ́n ti ń gbé aláìsàn tó wà lórí kẹ̀kẹ̀ aláìsàn lọ sí ilé ẹjọ́, ti ẹni bẹ́ẹ̀ kò leè dáhùn ìbéèrè Adájọ́ láti sọ bóyá òun jẹ̀bi tàbí òun kò jẹ̀bi."
Àwọn aṣojú-ṣòfin gbarata lórí ọ̀rọ̀ náà ṣùgbọ́n Dogara rọ̀ wọ́n láti fí ọkàn balẹ̀ nítorí àwọn aṣòfin àgbà tí ń yẹ ọ̀rọ̀ náà wò. Ní Ọjọ́bọ̀ ni àwọn ọlọ́pàá gbé Sẹ́nétọ̀ Dino Melaye lọ sí ilé ẹjọ́ lórí kẹ̀kẹ́ tí adájọ́ sì kọ̀ láti gba onídúró rẹ̀.Aṣòfin Karimi ni àwọn alágbára kan ni ìjọba ló ń dùn mọ̀huru mọ́ Dino nitori iha tó ń kọ sí ìjọba.








