Dino Melaye yóò wà ní àhámọ́ di ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹfà

Dino Mélayé

Oríṣun àwòrán, Salleh Ashaka

Àkọlé àwòrán, Ilé ẹjọ́ Kogi fi Dino Melaye sí àhàmọ́ tí'tí dí ọjọ́ ìgbẹ́jọ́

Gẹgẹ bí ìròyìn tó tẹ wá lọwọ, agbẹjọro Sẹ́netọ̀ Dino Melaye béèrè fún onídúró fún Sẹ́nétọ̀ náà ṣùgbọ́n adájọ tó gbọ́ ẹjọ́ náà kọ etí ikún sí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀.

Adájọ́ ní kí wọ́n fi Sẹ́netọ̀ Melaye sí àhámọ́ ọlọ́pàá di ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹfà tí ìgbẹ́jọ́ yóò tún wáyé.

Gideon Ayodele tó jẹ olùrànlọwọ fún Dino Melaye, lórí ọrọ ìròyìn ní, àti ránmú gángan ìdààmú Melaye, kò sẹyìn eekanna awọn alagbara kan ninu ijọba.

"Lootọ ni Adájọ tí so tirẹ̀, a ti gbà á gẹ́gẹ́ bíi ẹni tó bọwọ fún òfin; ṣugbọn a mọ̀ wí pé bi irọ ba lọ fún ògún ọdún, òtítọ yóò bá''

Sẹ́nétọ̀ to n soju ẹkun idibo Iwọ-oorun Kogi, ni ile Igbimọ Asofin agba lorilẹede Naijiria, Dino Melaye ti foju ba ile ẹjọ ni Lokoja.

Iroyin to tẹ wa lọwọ lati ọdọ oluranlowo rẹ̀ lori ọrọ iroyin, Gideon Ayodele so pe lowuro kutu ọjọbo ni wọn fi ọkọ gbe e kuro lati Abuja lo si Lokoja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

''Ni kete ti wọn de Lokoja ni wọn gbe Sẹ́nétọ̀ ninu ọkọ ti wọn fi n gbe alaisan lo si agọ ọlọpaa to wa ni ''A'' Division.''

O tẹ̀siwaju pe lẹyin igba naa ni wọn gbe e lọ si ile ẹjọ kekere ni Lokoja.

Ẹ maa ba wa kalọ fun ẹkunrẹrẹ iroyin lori isẹlẹ yii.