Dino Melaye: Adajọ fun ni beeli N100,000

Oríṣun àwòrán, Dino Melaye/Facebook
Ijọba apapọ ti gbe sẹnatọ Dino Melaye lọ Ile-Ẹjo ti Ijọba apapọ to wa ni Abuja, lori ẹsun wipe o parọ fun awọn ọlọpa wipe, awọn kan fẹ gba ẹmi oun losu Kẹrin, Ọdun 2017.
Wọn fẹsun kan Melaye wipe, o parọmọ Olori awọn Osise si Gomina Yahaya Bello ti ipinlẹ Kogi, Ọgbẹni Edward Onoja David wipe o ran awọn agbebọn lati wa gbẹmi oun.
Melaye, nigba to n jẹjọ sọwipe ohun o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun, lati Ọfisi Adajọ Agba fun orilẹede Naijiria, ni Ọjọ Kọkanlelọgbọn, Osu Kini, Ọdun 2018.
Sugbọn ninu idajọ rẹ, Adajọ Agba, Olasunbọ Goodluck gba beeli Melaye pẹlu ọkẹ marun Naira, N100,000 pẹlu oniduro kan, lẹyin ti o da ẹjọ naa nu lori wipe awọn ẹri ijọba apapọ ko lẹsẹ n lẹ.
Iroyin sọwipe awọn Sẹnatọ mọkanla lo tẹle Sẹnatọ Melaye lọ si ibi igbẹjọ Lọjọbọ, ti Sẹnatọ Ben Murray-Bruce ati Sẹnatọ Shehu Sani.








