Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí wọ́n rí Sẹ́nàtọ̀ Dino Melaye yọ nípò?

Aworan Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, Facebook/Dino Melaye

Àkọlé àwòrán, Dino Melaye ti kọ́kọ́ pè fún ìrànlọ́wọ́ ilé asòfin àgbà láti kojú ìpèníjà tó ń là kọjá

Àjọ elétò ìdìbò orìlẹ́èdè Nàìjíríá ní ohun gbogbo ti wà ní sẹpé láti sètò ìdìbò èyì tó lè mú kí àwọn olùdìbò yọ Sẹ́nàtọ̀ Dino Melaye nípò.

Sùgbọ́n kí ni irinsẹ́ ìyọni nípọ̀ ọ̀hún àti wí pé báwọ gaan ni wọ́n ti se ń se àmúlò rẹ̀?

Ẹ jẹ́ kí atibi pẹlẹbẹ mú ọ̀lẹ̀ jẹ.

Kíni ìgbésẹ̀ ìyọni nípọ̀

Lábẹ́ òfin Nàìjíríá , àwọn olùdìbò ní agbára láti yọ asojú tí wọ́n kò bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ kúrò nìpò sáájú kí àsìkò tì yóò lò nípò tó tó.

Aworan INEC gbe ilana eto idapada Senato Dino Melaye jade

Oríṣun àwòrán, Twitter/INEC

Àkọlé àwòrán, Ẹ̀yiǹ o rẹyiǹ ni àjọ INEC gbé ìlànà ètò ìdápadà Sẹ́nátọ̀ Dino Melaye jáde

Lóòótọ́ ni ànfààní yí wà nínú ìwé òfin orílẹ̀èdè Nàìjíríà sùgbọ́n ó sọ̀wọ́n kí àwọn òlùdìbò tó se àmúlò rẹ̀.

Nínú ìtàn Nàìjíríà, ìgbìyànjú àti yọ asojú kúrò nípò ti wáyé sùgbọ̀n kò sí àkọsílẹ̀ pé wọ́n t yọ ẹnìkankan kúrò nípò.

Lọ́jọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n Osù Kẹẹ́jọ ọdún 2005, ìbò ìyọninípò wáyé ní ìpínlẹ́ Plateau sùgbọ́n wọ́n kò ríbi yọ asojú náà nìtorí tí wọ́n kò ní iye ìbò tí wón ní lò.

Ìgbésè láti y asojú nípò

Abala mọ́kàndínláàdọ́ọ́ta ìwé òfin Nàìjíríà sọ pe kì wọ́n tó lè yọ asojú àwọn ìgbésẹ kan gbọ́dọ̀ sájú.

Mẹ́ẹ̀rin péré ni a ní ànfàànì láti sọ fún yín pẹ̀lù bí wón ti se setán láti yọ Dino nípò.

  • Àwọn olùdìbò tó ju ìlàjì àwọn tó forúkọ sílẹ̀ lẹ́kún Sẹ́nátọ̀ náà gbọ́dọ̀ kòwè, t'ọwọ́ bọ́wé kí wọn sí fi ìwé ẹ̀họ́nù wọn ránsẹ́ sí alága àjọ elétò ìdìbò pé àwọn kò ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú asojú náà mọ́.
  • INEC yó fi tó asojú náà létí pé ìwé ìyọninípò rẹ̀ ti tẹ àwọn lọ́wọ́ tí ìwé èhọ́nú nàá bá fẹsẹ̀mulẹ̀.
  • INEC yó sètò ìbò ìdánipadà láàárín àádóọ̀rún ọjọ́ tí o bá rí ìwé èhọ́nú gbà. Ibo sé ká yọ tàbí ká má yọ nípò ní àwọn olùdìbò yóò dì. Àwọn tí wọ́n sì jẹ́ olùdìbò tó forúkọ sílẹ̀ lẹ́kùún Sẹ́nátọ̀ náà ni yọ́ọ̀ kó pa.
  • Tí ọ̀pọ̀ àwọn olùdìbò bá fọwọ́ sí kí wọ́n yóò asojú náà, alága INEC yóò fi ìwé àsẹ ìpèpàdá ránsẹ́ sí Ààrẹ ilé ìgbìmò asòfin agbà.
  • Pàtàkì jùlọ, Ààrẹ ilé ìgbìmò asòfin agbà ni yóò kéde ìdápadà asojú tí wọ́n bá yo nípò .

Ìdàmù Dino Melaye

Ǹkan ò rọgbọ lẹ́nu ọjó mẹ́ta yìí fún ìlúmọ̀ọ́ká Sẹ́nátò orílẹ̀èdè Nàìjíríà Dino Melaye.

Melaye tó'ń sojú fún ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ Kogi ní a gbọ́ pé ìgbésè dídápadà rẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ ni ọjọ́ Ìsẹ́gun, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n osù yìí.

Aworan Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, Twitter/Dino Melaye

Àkọlé àwòrán, Ọ̀rọ̀ náà ti dójú sú Sẹ́nátò Dino Melaye tí óún kojú ọ̀pọ̀ ìpèníjà

Èyí kìí se ìgbààkọ́kọ́ ti Dino yóò níìpènìjà

  • Ní ìgbà tó jẹ́ asojú ilé ìgbìmọ̀ asòfin, wón pàsẹ lọ rọ́kún nílé fún òhun àti àwọn asòfin kan tí wọ́n kọ́pa nínú ìjà nínú ilé ìgbìmọ̀ asòfin
  • Àjọ Ọlọ́ọ̀pà orílẹ̀èdè Nàìjíríà fún Melaye di ọjọ́ 28, Osù Kẹẹ̀ta ọdún yìí láti yọjú sí àgọ́ ọlọ́ọ̀pá lórí ẹ̀sùn wípé àwọn ọ̀daràn méjì sọ́wípé Dino Melaye ni ọ̀gá àwọn tó ń rán àwọn nísẹ́ jàgídíjàgan.
  • Ìjọba àpapọ̀ wọ́ Dino Melaye lọ si ilé-ẹjọ́ ní Osù Kèrin, Ọdún tó kọjá lórí ẹ̀sun wípé ó parọ́ ijínigbé mó olórí àwọn òsìsé sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi, Yahaya Bello, Ọgbẹni Edward David nígbà tí Dino polongo wípeé àwọn kan fẹ́ sẹkú pa òun.