Election Update 2019: Àwọn adarí Africa fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Loju ewe awọn adari agbaye to n ki aarẹ Buhari ku oriire lati igba to jawe olubori gẹgẹ bi aarẹ Naijiria fun saa keji.
Eyi hande ninu atẹjade kan ti oluranlọwọ agba fun aarẹ lori ọrọ iroyin ati to kan araalu, Garba Shehu fi sita.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọba Mohammed kẹfa ti ijọba ilẹ Morocco ṣapejuwe yiyege aarẹ Buhari gẹgẹ bi aridaju igboya ti awọn ọmọ Naijiria ni ninu aarẹ wọn ti wọn si seleri lati ba a ṣiṣẹ fun agbega orilẹede.
"Atunyan ẹ jẹ ẹri si iru igboya ti o n janfani laarin awọn eniyan Naijiria to n safihan imọ rẹ ati iriri ninu oṣelu".
Oun funra rẹ naa wa tẹnu mọ ipinu rẹ lati ṣiṣẹ pọ pẹle aarẹ Buhari ki ajọṣepọ lee dan mọran laarin orilẹede Morocco ati Naijiria ki wn le jọ jẹ awokọṣe rere nilẹ Afirika.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakan naa, aarẹ Alpha Omar Conde ti orilẹede Guinea naa fi ọrọ ikini ranṣẹ si aarẹ Buhari. O ṣapejuwe atunyan rẹ gẹgẹ bi apẹrẹ ireti nla fun ẹkun Iwọ oorun Afirika.
Ọjọgbọn Conde ṣafihan aridaju igboya ti ibaṣepọ to dan mọran laarin Naijiria ati Guinea yoo mu tẹsiwaju.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣaaju, aarẹ Mahamadou Issoufou ti orilẹede Niger Republic lo jẹ adari to kọkọ pe aarẹ Buhari lati kii ku oriire ni iṣẹju perete lẹyin ti ajọ INEC kede rẹ gẹgẹ bi ajawe olubori ninu idibo aar ti ọdun 2019.
Mahamadou ni oun n foju sọna de ṣiṣe iṣẹ pọ pẹlu aarẹ orilẹede Naijiria lati tun mu okun ajọṣepọ laarin Naijiria ati Niger le dahin-dahin sii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ Buahri tun ti gba ikini latọdọ aarẹ Nana Akufo-Addo ti orilẹede Ghana to fi mọ aarẹ Macky Sall ti Senegal.












