Iléẹ̀kọ́ gbogboùnṣe ìgbájọ lé gíwá rẹ̀ lórí ẹ̀sùn ayédèrú ìwé ẹ̀rí

Akẹkọjade kan ninu aṣọ ikẹkọgboye rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọgbẹni Akinọla Ọlaolu ni oun gba iwe ẹri gboye ọmọwe ni fasiti ilu Ibadan ki iwadi to sọ pe ko ri bẹẹ

Igbimọ iṣakoso ileewe gbogboniṣe aladani kan nipinlẹ Ọun, Igbajọ Polytechnic ti le sga agba ileewe naa, Ọgbẹni Akinọla Olugbenga Ọlaolu ti wọn fi ẹsun kan pe o lo ayederu iwe ẹri ikẹkọ gboye smọwe lati fasiti Ibadan

Igbakeji alaga igbimọ majẹobajẹ ileẹkọ naa, Oloye Inaọlaji Abọaba to ba awọn oniroyin sọrọ lọgba ileewe naa ni nigba ti iroyin naa lu sita pe ayederu ni iwe ẹri imọ ijinlẹ ọmọwe ti ọgbẹni Akinọla Olugbenga Ọlaolu n gbe kiri ni wọn ti yara kọwe si fasiti Ibadan nibi ti o ni oun ti gba iwe ẹri naa lati lee fidi otitọ ọrs mulẹ.

" Abajade ifidimulẹ lati ọdọ awọn alaṣẹ fasiti Ibadan ni pe, kii ṣe ileewe naa ni iwe ẹri ti o n lo ti jade.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Waris Kareem: Emmanuel Macron kan sáárá lórí àwòrán tó yà

Igbimọ alakoso ileewe gbogboniṣe Igbajs ṣepade lori ọrọ naa nibẹ ni wọn si ti pinnu pe ki ọgbẹni Olugbenga Ọlaolu o fi ipo giwa ileewe naa silẹ."

Awo ọrọ nipa iwe ẹri Ọgbẹni Akinọla Olugbenga Ọlaolu lu sita ni ọsẹ diẹ sẹyin nigbati iroyin tan pe iwe ẹri ti o fi gba iṣẹ gẹgẹ bii giwa ileeks gbogbounṣe ilu Igbajọ kii ṣe otitọ ati pe arakunrin naa ko kẹkọ gboye ọmọwe, PhD ni fasiti ilu Ibadan