#Russia2018: Super Eagles dágbére fún ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé
Kò sí bí àjò ṣe fẹ́ rí, dájú dájú ilé làbọ̀ 'sinmi oko. Àwọn agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà ti parí iṣẹ́ tí wọ́n bá lọ sí Russia níbi ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé 2018.
Argentina ti y'ọwọ Nàìjírìa ninu idije ife ẹyẹ agbaye ti o n lọ lọwọ lẹyin ti Argentina fun wọn ni ami ayo meji si ẹyọkan 2-1.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:
Nínú ìdíje tí wọ́n gbá kẹ́yìn, Lionel Messi lo kọkọ gbayo wọle fun Argentina ki Victor Moses to da a pada fun Nàìjírìa pẹlu pẹnáritì.
Marcos Rojo lo gba ayo keji wọle ti Argentina fi jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.









