Chelsea fi ojú Manchester United gbólẹ̀, gba ife ẹ̀yẹ FA

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ́lù Chelsea ti jáwé olú borí nínú ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹ̀lú Manchester United tí ó jẹ́ẹ̀ àṣekágbá idíje FA ní pápá ìṣeré Wembley.
Àyo kan sí òdo ni Chelsea gbá pẹlú Manchester United. Eden Hazard ní ó gba ayò náà wọle tí ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ ran Jose Mourinho tí ó jẹ́ olùdarí ẹgbẹ́ agbá bọ́ọ̀lù Manchester United lọ ilé ní ọwọ́ òfo.
Óṣeéṣe kí akọ́nimọ̀ọ́gbá ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Chelsea Antonio Conte kí o fi ibẹ̀ sílẹ̀ láàpẹ́ yìí. Wọn ti ni ẹ̀bun idágbére ni ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ fun.








