Idibo 2019: Ajọ Ọdọ Yoruba fa'gile iwọde fun aarẹ Buhari

Awọn ọmọ ẹgbẹ ọdọ Yoruba to ga ju lọ lagbaye - Yoruba Youth Congress (YYC)

Oríṣun àwòrán, YORUBA YOUTH CONGRESS

Àkọlé àwòrán, Eto oselu ti nda wahala silẹ laarin awọn ọdọ

Ẹgbẹ awọn ọdọ Yoruba to ga ju lọ lagbaye - Yoruba Youth Congress (YYC) ti wẹ ara wọn mọ kuro ninu iwọde, Yoruba Youth Rally, ti awọn ẹgbẹ kan fẹ se lati polongo idibo ẹlẹkeeji fun aarẹ Muhammadu Buhari lọdun 2019.

Ẹgbẹ awọn ọdọ to ga ju gbe ọrọ naa jade ninu atẹjade ti olori ẹgbẹ naa, Ẹric Oluwọle ati akọwe ẹgbẹ, Lekan Shobowale fọwọsi, ti wọn si gbe jade fun awọn akọroyin ni Akurẹ, nipinlẹ Ondo.

Ẹgbẹ naa wi pe awọn ko nii nnkan kan se pẹlu iwọde fun aarẹ Buhari, pẹlu alaye wi pe ẹgbẹ ti o gbe iwọde naa kalẹ, Progressive Peoples Congress jẹyọ latara ẹgbẹ oselu kan, ti awọn ko nii darukọ rẹ. Ati wipe ọgbẹni Pẹlumi Amọdu to jẹ adari ẹgbẹ naa kii se asoju tabi osisẹ fun ẹgbẹ ọdọ Yoruba lapapọ.

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Àkọlé àwòrán, Aarẹ Buhari ko tii sọ boya yoo gba'poti idibo lẹẹkeji lọdun 2019

Ninu ọrọ rẹ, Oluwole sọ pe asiko ti wọn gbe iwọde naa kalẹ ko bojumu nitori ipaniyan ati isekupani ti o n waye lawọn agbegbe kan lorilẹede Naijiria.

Awọn ọdọ naa wa parọwa si awọn agbaagba ẹkun Yoruba lati mase fi owo yẹpẹrẹ mu awọn ọdọ, bẹẹsi ni ki ijọba apapo kọbi ara si ọrọ aje to dẹnu kọle lorilẹede yi. Wọn si rọ ijọba apapọ lati mase fikun owo epo bentiroolu.