Arun iba ọrẹrẹ: ipinlẹ Anambra pasẹ ma mu Gaari mọ

Aworan ekute

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Igbẹ ati ito eku ninu garri a ma fa iba ọrẹrẹ

Lati dẹkun arun iba ọrẹrẹ to gbode kan, Ijọba ipinlẹ Anambra ti pasẹ ki awọn ara ilu ma mu gaari mọ.

Wọn ni o le fa arun iba ọrẹrẹ, Lassa Fever.

Kọmisọna fun eto ilera nipinlẹ naa sọ pe ''gaari ti wọn tẹ kalẹ loju titi marose lewu ni mumu.'' O fi kun ọrọ rẹ pe ọpọ iru garri bayi ni o se e se ki aleebu ti baa.

Ajọ eleto ilera agbaye sọ pe ọunje ti ekute yagbẹ si tabi to tọ si a maa sokunfa itanka arun naa.

Garri jẹ ounjẹ to gbajumọ laaarin awọn ọmọ orilẹede yi. Bi wọn ba yan gaari ọhun daradara o se e se ki kokoro to'n fa iba ọrẹrẹ naa ku.

Sugbọn ọpọlọpọ lo fẹran gaari ni mumu.

Lẹnu ọjọ mẹta yi, aisan iba ọrẹrẹ gbale kaakiri orilẹede yi. Lọjọ aiku ni onimọ ilera kan salaisi nipinlẹ Edo nigba ti o ko aisan naa lara ọmọ kan.