Aisha Buhari: Òlùrànlọ́wọ́ pàtàkì fi orúkọ mi gba owó

Aisha Buhari

Oríṣun àwòrán, @aishambuhari

Àkọlé àwòrán, Aisha Buhari

Ìyàwó ààrẹ orílẹ̀èdè Nàìjíríà, Aisha Buhari ti pàṣẹ pé kí ajọ ọ̀télẹ̀múyẹ́ DSS gbé olùrànlọ́wọ́ pàtàkì ti mọlé rẹ̀ lórí ẹ̀sùn pé ó jà a lólè biliọnu meji aabọ

Gẹ́gẹ́ bí àwọ́n tó mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe fi tò ìwé ìròyìn Premium Times létí, ìyàwò ààrẹ ń fi ẹ̀sùn kan pé ṣe ni arákùnrin náà fí orúkọ òun jalè.

Ìyàwò ààrẹ ń fi ẹ̀sùn kan pé ṣe ni Sani Baba-Inna tó jẹ́ ọ̀gá ọlọ́pàá gba owó mọ̀dá-mọ̀dá gọbọi lọ́wọ́ àwọn olóṣèlú àtàwọ́n oníṣòwò lórúkọ rẹ̀ tó sì kó o sápò ara rẹ̀.

Fún ìdí èyí ni arábìnrin Buhari pàṣẹ pé kí ọ̀gá àgbà àwọn ọlọ́pàá, Ibrahim Idris fi òfin mú Ọ̀gbẹ́ni Baba-Inna láti dá owó náà padà èyí tí ó tó bílíọ̀nù méjì àbọ̀ Náírà.

Wọ́n ti mú ọlọ̀pàá náà ni ọjọ́ ẹtì ó sì ti wà ní àtìmọ̀lé ọlọ́pàá láà fààyè gbà kí ẹbí kankan fojú kàn an gẹ́gẹ́ bí àwọ́n ẹbí rẹ̀ ṣe sọ.

Kò hàn gedegbe bí ìyàwó ààrẹ ṣe gbé ẹ̀sùn náà síta súgbọ́n ènìyàn kan ló ta olobó pé olùrànlọ́wọ́ pàtàkì míì tó ń ṣiṣẹ́ fún ìyàwó ààrẹ ló pilẹ̀sẹ̀ rẹ̀.

Ẹ̀wẹ̀, ẹlẹgbẹ́ ọlọ́pàá yìí kan sọ pé Ọgbẹ́ni Baba-Inna fẹ̀sẹ̀ múlẹ̀ pé òun kò lọ́wọ́ sí ẹ̀sùn yìí rárá wí pé òun kò gba owó kankan lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni lórukọ ọ̀gá òun.

Àkọlé fídíò, Adeleke fọhùn, 'èmi ni gómìnà tí wọ́n dìbò yàn'

Àbábọ̀ ìwádìí Ọlọ́pàá

Ní kété ti ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá tẹ́wọ́ gba ìwé látọ̀dọ̀ arábìnrin Buharí ni wọ́n mú olùrànlọ́wọ́ náà tí ìwádìí sì bẹ̀rẹ̀.

A gbọ́ pé ọ̀gá àgbà àwọn ọlọ́pàá ní wọ́n gbúdọ̀ ṣe ìwádìí ọ̀rọ̀ náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà sì ni wọ́n bá ya lọ ilé olùrànlọ́wọ́ ọ̀hún.

Sùgbọ́n kàyéfì ńlá ló jẹ́ wí pé ẹgbẹ̀fà Náìrà nìkan ni owó tí ikọ̀ aṣéwádìí yìí bá nínú ilé rẹ̀. Bákan náà wọ́n yẹ àpò ìsúná rẹ̀ wò, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ́n Náírà péré ló kù síbẹ̀.

Bákan náà, àkọsílẹ̀ fihàn wí pé ọ̀pọ̀ owó tó ń wọ àpò ìsúná rẹ̀ jẹ́ owó oṣù àti àwọn àjẹmọ́nú rẹ̀.

Nítorínáà, àwọn ọlọ́pàá wòye wí pé ìròyìn àìtọ́ ni.