Valencia vs Chelsea: Oró tó dá mi ni mo dá ọ ni Chelsea àti Valencia fi ṣe fún ra wọn

Awọn agbabọọlu Valencia ati Chelsea

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aileja lojude ile baba mi ko de ibi. Bẹẹ gan lọrọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ṣe ri lẹyin ti wọn tẹyin ta ọmi alayo mejimeji pẹlu Valencia ninu idije UEFA Champions League lalẹ Ọjọru.

Awọn ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji kọkọ gbiyanju agbara wọn ṣugbọn ko sẹni to gbayo sawọn ẹnikeji fun iṣẹju mọkandinlogoji.

Ṣugbọn Valencia lo kọkọ gbayo sawọn Chelsea lẹyin ti Carlos Soler jẹ goolu akọkọ nigba ti ifẹsẹwọnsẹ ọhun di ogoji iṣẹju.

Amọ, Mateo Kovacic dayo naa pada lẹyin iṣẹju kan pere, eyi to mu ere bọọlu naa di ọmi alayo kọọkan.

Lẹyin iṣẹju marun un ti ipele keji ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ ni Christian Pulisic fọba lee fun Chelsea ti ifẹsẹwọnsẹ si di ami ayo meji sẹyọkan fun Chelsea.

Valencia lanfaani lati gbayo mii sawọn lẹyin ti rẹfiri fun wọn ni pẹnariti, ṣugbọn aṣọle Chelsea Kepa Arizabalaga mu pẹnariti ọhun.

Gbogbọ igbiyanju Valencia lati ta ọmi ninu ere bọọlu ọhun, ja si ayọ nigba ti Daniel Wass tayo naa fi di 2-2.