Germany vs South Korea: Loew ni 'Ó dáa bí wọ́n ṣe nà wá'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijakulẹ Germany lọwọ South Korea nínú ìdíje àgbáyé Russia ṣì ń kàn àti olórí àti ọmọ ilẹ náà ní lominu.
Ayo méjì sodo ní South Korea fi gbo ewuro sojú ìkọ agbaboolu Germany to ṣe wi pé àwọn ni wọn gbà ife ẹyẹ àgbáyé kẹyin.
Angela Merkel to je olórí ìjọba lorílè-èdè Germany ni inú oun bajẹ pẹlú ìṣẹlẹ náà ti ojú òpó Twitter ìjọba orílẹ̀-èdè náà sì ṣe àpèjúwe ijakulẹ Germany gẹgẹ bí òun tó pesi jẹ.

Àfọwọ́fà wá ní
Olukọni ìkọ Germany Loew so pé nnkan tó yẹ ìkọ òun ní ijakule náà.
''Afowofà wá ní. Nínú ìdíje yìí, a kò ṣebi ẹni tí mùṣùmúṣè rẹ gbà múṣé rara''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
''Òun taa fí ọwọ wa fa ni ijakule yìí.''
Èyí ni ìgbà èkejì ti Germany fidiremi nínú ìdíje àgbáyé l'abala kinni.
Ọdún 1938 ni irú ijakule yi tí wáyé kẹyìn fún orílè-èdè náà.
Sweden ati South Korea lo tẹ̀síwájú ló abala kejì lati ìsòrí wọn.
















