Sepp Blatter: Jíjọ gbàlejò ife àgbáyé kò dáa tó

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ààrẹ àná àjọ tó n rí sí eré bọ́ọ̀lù lágbayé, Sepp Blatter ni òun l'òdì sí jíjọ gba àlejò ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé.
Blatter ni FIFA fẹ kí àwọn orílẹ̀-èdè jumọ gbalejo idije naa ní torí pé wón fé so ìyè orílèèdè to n kópa sí méjìdínlàádọta.
O tẹnumọ adisọkan rẹ pé orílèèdè kan ṣoṣo ló yẹ kó gbà àlejò ife ẹyẹ náà dipo bi awọn orílèèdè kan ṣe n gbèrò láti jọ gbalejo ìdíje òun.
''...Ki orílèèdè mẹta jíjó gbalejo idije náà... nígbà tí wọn tó gbangba sùn lọ̀yẹ́ kíni won wa fẹ jumọ gbalejo ìdíje náà fún?''
Orílèèdè America,Canada ati Mexico n gbèrò láti jíjó gbalejo ìdíje àgbáyé ọdún 2026.
Ọjọ ọjọ kẹ̀tàlá oṣù kẹfà ni wọn yóò kéde ìpinu lórí ìgbésẹ náà.
Blatter ṣe àkóso èrè bọọlu lágbayé fún ọdún mẹ́tàdínlógún kí wọn to yọ kúrò nípò lórí ẹsùn ikowoje.








