CAF: Naijiria ni asoju ẹgbẹ agbabọọlu mẹrin

Awọn agbabọọlu mẹta n figagbaga

Oríṣun àwòrán, Nigeria League Management company

Àkọlé àwòrán, O ti pẹ diẹ ti orilẹede Naijiria ti gba ife ẹyẹ awọn ẹgbẹ agbabọọlu ni ilẹ Afirika kẹyin
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ikọ agbabọọlu mẹrin ni yoo maa gbe asia orilẹede Naijiria ninu idije ife ẹyẹ CAF Confederation Cup bayii.

Awọn ikọ agbabọọlu naa ni MFM, Plateau United, Enyimba ati Akwa United.

Eyi si ni igba akọkọ ninu itan idije naa ti orilẹede Naijiria yoo maa ni ikọ agbabọọlu mẹrin ọtọọtọ ninu idje naa.

Eyi ko sa dede waye bikose pẹlu bi ẹgbẹ agbabọọlu MFM ati Plateau united to n soju orilẹede Naijiria tẹlẹ ninu idije CAF champions league se fidirẹmi lopin ọsẹ.

Agbabọọlu n gba bọọlu lati wọle

Oríṣun àwòrán, Nigeria League Management company

Àkọlé àwòrán, Iroyin ayọ ni fun orilẹede Naijiria latọdọ awọn ikọ ẹgbẹ agbabọọlu to kopa ni idije Confederations cup

Ẹgbẹ agbabọọlu MC Algers fi iya jẹ MFM pẹlu ami ayo mẹfa si odo lati ja kuro ni idije Champions league.

Bẹẹ naa ni ami ayo kan ti Plateau United fi gbẹyẹ lọwọ Etuile du Sahel ko to lati pa ami ayo mẹrin si meji ti Etuile fi gbẹyẹ mọ wọn lọwọ ni abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ naa to waye lorilẹede Tunisia saaju rẹ.

Iroyin ayọ ni lẹkunrẹrẹ fun orilẹede Naijiria latọdọ awọn ikọ ẹgbẹ agbabọọlu to kopa ninu idije Confederations cup lati ibẹẹrẹ pẹpẹ, iyẹn Enyimba ati Akwa United.

Enyimba na Energie lati orilẹede Benin pẹlu ayo mẹta si meji eyi to sọ gbogbo ayo ti wọn gba di marun si meji.

Akwa united pẹlu na Al ittihad pẹlu ayo mẹta si meji ni ipele gbe silẹ ko gba sile Penalties lẹyin ti wọn ta ọmi.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Idije Liigi Naijiria

Bakanaa ni idije liigi premiership orilẹede Naijiria waye lopin ọsẹ to kọja.

Lẹyin ifẹsẹwọnsẹ to waye, ẹgbẹ agbabọọlu Lobi stars, kano Pillars ati Akwa United lo di ipo kinni, ikeji ati ikẹta mu nigbati Kwara United, Go Round, Heartland ati FC Ifeanyi Uba wa ni isalẹ tabili igbelewọn liigi orilẹede naijiria.

Atẹ igbelewọn liigi premiership orilẹ̀ede Naijiria.

Orisun: League Management Company, LMC