Ọbabinrin wàjà, wọ́n ń ṣọ̀fọ̀ ní ààfin

Ọbabinrin Elizabeth Kejì wàjà, ààfin Buckingham ń ṣọ̀fọ̀

Queen Elizabeth

Ọbabinrin Elizabeth Keji, to jẹ ọba to pẹ lori oye julọ nilẹ Gẹẹsi ti jade laye lẹni ọdun mẹrindinlọgọrun, lẹyin to jọba fun aadọrin ọdun.

Awọn mọlẹbi rẹ pejọ pọ si aafin rẹ lẹyin ti iroyin jade nipa ilera ara rẹ.

Ọdun 1952 ni Ọbabinrin naa gori itẹ, ti ohun gbogbo si yipada si rere.

Ilu Balmoral ni Ọbabìnrin Elizabeth Keji, to jẹ ọba alade to pẹ ju lori ìtẹ́ ni UK dakẹ si, lẹyin aadọrin ọdun to joyè.

 Gbogbo ẹbi rẹ lo kóra jọ pọ si ile rẹ ni Scottish Estate lẹyin ti awọn dokita kede pe ipo ilera rẹ kò fi awọn ni ọkan balẹ.

 Ọdun 1952 ni ọbabìnrin naa gun ori itẹ, ọpọlọpọ ayipada awujọ lo sì waye nigba rẹ.

Ọmọ rẹ ọkunrin to dagba ju, Charles, si ti di Ọba Charles Kẹta, ati olori fun awọn orile-ede mẹrinla to wa ninu àjọ Commonwealth.

 Ọba Charles sọ pe 'asiko ibanujẹ nla' ni iku iya oun jẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu ikede to fi sita, Ọba Charles sọ pe "a n ṣe ọ̀fọ̀ ipapoda ori adé to ṣe iyebíye, to tun jẹ iya ti a fẹ́ràn pupọ.

 " Mo mọ pe jakejado orile-ede yii ni iku rẹ yoo jẹ ibanuje, ninu ajọ Commonwealth, ati laarin àìmọye eeyan ni gbogbo ayé."

 O ni sugbọn apọnle, ọ̀wọ̀ ati ifẹ ti àwọn eeyan ni si Ọbabìnrin, yoo jẹ itunu ati imulọkanle fun oun ati ẹbi oun lasiko ọ̀fọ̀ yii.

Lẹyin iku rẹ yii, Arẹmọ rẹ, Ọba Charles gori oye gẹgẹ bi ọba tuntun ati adari orilẹede mẹrinla labẹ Ajọ Commonwealth.

Ninu atẹjade kan ti Buckingham Palace fi lede, o ni Ọbabinrin naa waja lọwọ ọsan pẹlu irọrun ni aafin Balmoral.

Ọba ati Olori rẹ yoo wa ni Balmoral ni irọlẹ yii ti wọn yoo si pada si ilu ọba, London ni ọla.

Gbogbo awọn ọmọ ọba ni wọn pada si Balmoral, to sun mọ Aberdeen lẹyin ti dokita kede ara ọrọ fun ilera ọbabinrin naa.

Ọmọ-ọmọ rẹ, Prince Willam wa nibẹ pẹlu Ọmọbakunrin Harry wa ni ọna.

Aafin to wa ni Buckingham naa sọ ninu atẹjade pe" wọrọwọ ni Ọbabìnrin ku si Balmoral lọsan oni.

 "Balmoral si ni Ọba ati olori rẹ yoo sun mọju, ki wọn to pada silu London ni ọla."

 Gbogbo awọn ọmọ Ọbabìnrin lo rinrinajo lọ si Balmoral, to wa nitosi Aberdeen, lẹyin ti awọn dokita rẹ fi si abẹ amojuto to lagbara."

 Ọmọ-ọmọ rẹ, Ọmọba William naa wa nibẹ, ti aburo rẹ, Harry sì wa lọna.

 Olootu ijọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Liz Truss, ti Ọbabìnrin fi joye ni ọjọ Iṣẹgun, sọ pe ori ade naa ni àpáta ti wọn kọ́ orile-ede Britain igbalode si,

'O ti pese ìdúró ṣinṣin ati okun ti a nílò fun wa".

 Arábìnrin Truss sọ pe awọn yoo jẹ olotitọ ati olufọkansin si ọba tuntun, gẹgẹ bi iya rẹ ṣe fi taratara sin ọpọlọpọ fun ọjọ́ pipẹ.

Olootu ijọba nilẹ UK, Liz Truss n sọrọ niwaju ile ijọba

Oríṣun àwòrán, PA Media

Àkọlé àwòrán, Olootu ijọba nilẹ UK, Liz Truss ni iku Ọbabinrin jẹ eyi to ba orilẹede naa ati awujọ agbaye lojiji

Àwọn iṣẹlẹ bi opin ogun Cold War, bi UK ṣe darapọ mọ àjọ ilẹ Yúróòpù ati bo ṣe kuro nibẹ, to fi mọ idasilẹ àjọ Commonwealth, lo waye lasiko ìjọba Ọbabìnrin Elizabeth.

 Olootu ijọba ilẹ̀ UK mẹẹdogun lo jẹ lasiko rẹ, bẹ̀rẹ̀ lati ori Winston Churchill ti wọn bi lọdun 1874 de ori Arábìnrin Truss, ti wọn bi lẹyin ọdún mọkanlelọgọrun.

 Lọsọọsẹ lo ma n ṣe ipade pẹlu awọn olootu ijọba rẹ titi to fi kú.

Ni aafin Buckingham nilu London, awọn ero to ti duro tẹlẹ lati gbọ ipo ti ilera Ọbabinrin wa, lo bu sẹkun nigba ti wọn gbọ iku rẹ.

Lati aago mẹfa abọ ni wọn ti fa asia orilede naa wa silẹ niwaju aafin, ti wọn si ran osisẹ aafin kan lọ sita lati lọ kede iku Ọbabinrin fun wọn.

Nibayii ti Ọbabinrin ti papoda, Ọmọọba William ati aya rẹ, Catherine ni yoo di Duke ati Duchess ti Cambridge ati Cornwall.

Akọle iku Ọbabinrin Elizabeth

Oríṣun àwòrán, Reuters

 Ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 1926 ni wọn bi Alexandra Mary Windsor, to pada di Ọbabìnrin Elizabeth.

 Àwọn to ro o pe o le di ọba ko pọ, sugbọn ni oṣu Kejila, ọdun 1936, ẹ̀gbọ́n baba rẹ Edward VIII, kọ ìtẹ́, ko le raaye fẹ ọmọ ilẹ America, Wallis Simpson.

Baba Elizabeth jẹ́ Oba gẹ́gẹ́ bii King George VI nigba naa.

Lilbet ni oruko ti ọ̀pọ̀ n pe Elizabeth ni asiko yii.

Nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹ́waa pere ni won ti mọ pe ori ade ni lẹyin ti baba rẹ̀ ba papoda tan.

Odun mẹ́ta leyin eyi ni Britain bẹ̀rẹ̀ ogun pelu Nazi ni orile-ede Germany.

Elizabeth ati aburo rẹ̀, Omoobabinrin Margaret lo asiko to pọ̀ ni Winsdor Castle ni gbogbo igba ogun yii lẹ́yin ti awọn Obi wọn kọ̀ pe ki wọ́n ko awon omo naa ransẹ́ si Canada.

Ni kete ti Elizabeth pe eni ọdun mejidinlogun lo lọ si Auxilliary Territorial Services lati sisẹ́ fun osu marun un to si kọ́ isẹ́ mekaniiki atun ọkọ̀ se pẹ́lu ọks wíwà.

O ni pe: Mo bẹ̀rẹ̀ si ni kọ́ nipa “espirit de corps to n mu ni burẹ́kẹ́ ninu làásìgbò aye”

Lasiko ogun yii naa ni oun ati ibatan re, Omooba Philip ni Greece to n sin ilẹ̀ rẹ̀ ni Royal Navy.

Ibasepọ̀ wọn di nla ni eyi to jasi igbeyawo ni ogunjọ́ osu kokanla, ọdun 1947 ni Westminster Abbey.

Nibi igbeyawo yii ni omooba Philip ti gba oye Duke of Edinburgh.

Lẹ́yin o reyin ni Elizabeth sapejuwe Philip gẹ́gẹ́ bii igi lẹ́yin ọgba rẹ̀ ati agbara rẹ́ ninu odun merinlaadorin ti wọn jọ gbe papọ̀ ni lọ́kọlaya ki ọlọ́jọ́ to de fun Philip ni ọdun 2021 lodun mokandinlọ́gọ́run un.

Ọmọọba Phillip ati Ọbabinrin Elizabeth

Oríṣun àwòrán, TIM GRAHAM/PA

Charles ni akọbi ọmọ ti wọ́n kọ́kọ́ bi lọ́dun 1948. Leyin naa ni Omoobabinrin Anne ni 1950, ki wọ́n to tun bi Andrew ni ọdun 1960 ati Edward ni ọdun 1964.

Laarin wọ́n, wọ́n bi ọmọ ọmọ mẹ́jọ ati ọmọ ọmọ ọmọ iran keta mejila.

Orile-ede Kenya ni Elizabeth wa lodun 1952 nigba ti o n soju Oba to jẹ́ baba re nigba naa ni ọkọ rẹ, Philip tufọ iku baba rẹ̀ fun un.

Lesekese ni Elizabeth pada si London gẹ́gẹ́ bii Obabinrin tuntun.

O ni pe: “Iroyin naa ba mi lojiji, mo gba kadara lati sa ipa mi gidigidi.”

Ni ọjọ̀ keji, osu kẹ́fa, ọdun 1953 ni wọ́n gbe ade le Elizabeth lori leni ọdun mẹ́tadinlọ́gbọ̀n.

 O le ni ogun milionu eeyan ti wọ́n wo ayẹyẹ igbade Elizabeth gẹ́gẹ́ bii Obabinrin ilẹ̀ Geesi.

Opọ̀lọpọ̀ ayipada rere lo sẹlẹ̀ lẹ́yin ti Elizabeth gba ade.

Obabinrin yii mu atunto ba ile Oba nipase biba awọn ara ilu sọ̀rọ̀ loorekoore.

O tun maa n se abẹ̀wo sile ọla ati lilo si awon ipade itagbangba yato si ifọkansin rẹ̀ si ajọ isọ̀kan agbaye to jẹ́ Commonwealth nibi to sabẹ̀wo si lawon orile-ede.

Asiko ibanuje ni gbangba ati ni kọ̀rọ̀ sẹlẹ̀ si Obabinrin Elizabeth naa gẹ́gẹ́ bii ti gbogbo elẹ́ran ara.

Ni ọdun 1992 lasiko “Annus Horribilis” ni ina deede sọ ni Winsdor Castle to jẹ́ ibugbe ati aafin ibi isẹ́. Leyin naa ni igbeyawo awọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta koju isoro.

Leyin iku Omoobabinrin Diana, to je ti Wales ninu ijamba ọkọ̀ ni orile-ede Paris lọ́dun 1997 ni ibanuje tun ba Elizabeth sii.

Opọ awọn ara ilu lo bẹnu atẹ lu Elizabeth pe ko tete sọ̀rọ̀ nipa isẹlẹ naa.

Ti awọn eeyan si n sọ orisiirisii nkan sii sugbọn Elizabeth sọ pe: “ Ko si eni naa paapaa ori ade ti ko ni ri iru ariwisi bayii lati ọ̀dọ̀ awon to n satilẹ̀yin fun un, ti wọ́n ni ifẹ́ rẹ̀ ki a to sẹ̀sẹ̀ sọ lati ọ̀dọ̀ awon ti wọ́n ko se bẹ́ẹ̀ fun un.”

Baba ati iya Ọbabinrin Elizabeth gbe lọwọ

Oríṣun àwòrán, PA Media

Eni ọdun mọkanlelogun ni Elizabeth nigba ti o seleri lati jọ̀wọ́ aye rl lati fi sin orile-ede re ati agbaye.

Nigba ti o n sasaro lori igbe aye rẹ̀ ni ọdun diẹ̀ seyin lasiko ayeye ọdun mẹ́ẹ̀dọ́gbn lori itẹ́ ni 1977, O ni pe: “Emi ko kabamọ ileri ti mo se ati ẹ̀jẹ́ ti mo jẹ́ nigba èwe mi rara bo tile jẹ́ pe mo kere nigba naa”.

Ibura ati ifọkansin kan naa ni Obabinrin Elizabeth se ninu lẹta idupe to kọ si awọn ara ilu lọ́dun marundinlaadota leyin naa lasiko to n sami aadorin ọdunlori oye losu kẹfa to kọ́ja.

Opolọ̀pọ̀ nkan ni wọ́n fi sami ayeyẹ aadorin ọdun yii ni gbogbo opopona ati kaakiri ilẹ̀ United Kingdom.

Nitootọ, agba ti n de ni eyi ti ilera Obabinrin ko si fun un loore ọ̀fẹ́ lati kopa ninu diẹ̀ lara awọn eto akanse naa sibẹ̀ o fi ọ̀rọ̀ ransẹ́ pe '"ọkan mi wa lara gbogbo eeyan lasiko ayẹyẹ naa."

Awọn ididle rẹ to jẹ iran mẹta to wa ni aafin Buckingham dara pọ mọ ni gbagede ile naa fun asekagba idije orekelẹwa.

Ọbabinrin ni gbagede aafin Buckingham pẹlu iran rẹ mẹta

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lasiko ayẹyẹ igbade aadọrin ọdun to dori itẹ, Ọbabinrin mu inu awọn eeyan dun pẹlu bo se yọju si wọn ni gbagede aafin pẹlu iran mẹta ninu ẹbi rẹ

Oba Charles je eni ọdun metalelaadọrin bayii.

O ti di olori ajọ isokan Commonwealth ti ẹlẹ́ẹ̀kẹrinla.

Charles ati aya rẹ̀, Camilla ti wa ni Balmoral pẹ̀lú awon aburo re, iyẹn Omoobabinrin Anne, Omooba Andrew ati Edward ti wa nibe.

Awon mii to wa nibẹ̀ pẹ̀lu wọn ni Sophie to je aya Edward, ati Omooba William ati Harry ti wọ́n je ọmọ ọmọ Obabinrin Elizabeth.

Catherine to jẹ́ aya William si wa nile ni Winsdor nibẹ̀ pẹ̀lu George, Charlotte ati Louis nitori pe oni ni ile ẹ̀kọ́ wọ́n sẹ̀sẹ̀ wọle ni ile ẹ̀kọ́ tuntun.

Mọto kan ti Ọmọọba Andrew ati Ọmọọba Edward wa ninu rẹ

Oríṣun àwòrán, PA Media

Àkọlé àwòrán, Ọmọọba William n wa awọn agbaagba idile ọba - to fi mọ Ọmọọba Chariles ati Ọmọọba Edward - lọ si Balmoral
Ọmọọba Harry ninu mọto kan

Oríṣun àwòrán, PA Media

Àkọlé àwòrán, Ọmọọba Harry gunlẹ si Balmoral lati dara pọ mọ awọn asaaju ninu idile ọba

Ile Oba naa ti wa ni asiko ìdárò bayii.

Ko ni si eto afẹfẹ yẹ̀yẹ̀ kankan nitori pe won yoo wọ́gile gbogbo inawo tabi ayẹyẹ to wa tẹ́lẹ̀.

Asia Union flag ni wọ́n yoo sọ̀ kalẹ̀ ni gbogbo Aafin Oba ati ile Oba, pelu ni gbogbo ile ise ijoba ati lọ́dọ̀ awon ologun ati gbogbo ibudo United Kingodm ni ile okeere.

Awon Adari orile-ede agbaye lorisiirisii lo ti n ba ile Oba kedun ni United Kingdom.

Lara won ni Aare Joe Biden lati ile Amerika, o se iranti bi Obabainrin Elizabeth se duro ti America lasiko ikọlu agbesunmọmi 9/11 nigba naa.

Emmanuel Macron to je aare ilẹ̀ Faranse sapejuwe Obabinrin pe o jẹ́ Obabinrin to laanu loju to si jẹ́ ọ̀rẹ́ fun orile-ede France.